Malaki 4 - Bibeli MimọỌjọ́ OLUWA ń bọ̀ 1 SA kiye si i, ọjọ na mbọ̀, ti yio ma jó bi iná ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yio dabi akékù koriko: ọjọ na ti mbọ̀ yio si jo wọn run, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti kì yio fi kù gbòngbo tabi ẹka fun wọn. 2 Ṣugbọn Õrùn ododo yio là, ti on ti imularada ni iyẹ́-apá rẹ̀, fun ẹnyin ti o bẹ̀ru orukọ mi; ẹnyin o si jade lọ, ẹnyin o si ma dagba bi awọn ẹgbọrọ malu inu agbo. 3 Ẹnyin o si tẹ̀ awọn enia buburu mọlẹ: nitori nwọn o jasi ẽrú labẹ atẹlẹsẹ̀ nyin, li ọjọ na ti emi o dá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 4 Ẹ ranti ofin Mose iranṣẹ mi, eyi ti mo pa li aṣẹ fun u ni Horebu fun gbogbo Israeli, pẹlu aṣẹ ati idajọ wọnni. 5 Wò o, emi o rán woli Elijah si nyin, ki ọjọ nla-nlà Oluwa, ati ọjọ ti o li ẹ̀ru to de: 6 Yio si pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ọkàn awọn ọmọ si ti awọn baba wọn, ki emi ki o má ba wá fi aiye gégun. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria