Lefitiku 8 - Bibeli MimọÌyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀ ( Eks 29:1-37 ) 1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati ẹ̀wu wọnni, ati oróro itasori, ati akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo meji, ati agbọ̀n àkara alaiwu kan; 3 Ki iwọ ki o si pè gbogbo ijọ enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 4 Mose si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u; a si pe awọn enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 5 Mose si wi fun ijọ enia pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ lati ṣe. 6 Mose si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá, o si fi omi wẹ̀ wọn. 7 O si wọ̀ ọ li ẹ̀wu, o si fi amure dì i, o si fi aṣọ igunwa wọ̀ ọ, o si wọ̀ ọ li ẹ̀wu-efodi, o si fi onirũru-ọ̀na ọjá ẹ̀wu-efodi dì i, o si fi gbà a li ọjá. 8 O si dì igbàiya mọ́ ọ; o si fi Urimu ati Tummimu sinu igbàiya na. 9 O si fi fila dé e li ori; ati lara fila na pẹlu, ani niwaju rẹ̀, li o fi awo wurà na si, adé mimọ́ nì; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 10 Mose si mú oróro itasori, o si ta a sara agọ́, ati sara ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, o si yà wọn simimọ́. 11 O si mú ninu rẹ̀ fi wọ́n ori pẹpẹ nigba meje, o si ta a sara pẹpẹ na, ati si gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, lati yà wọn simimọ́. 12 O si dà ninu oróro itasori si ori Aaroni, o si ta a si i lara, lati yà a simimọ́. 13 Mose si mú awọn ọmọ Aaroni wá, o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn, o si fi amure di wọn, o si fi fila dé wọn li ori; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 14 O si mú akọmalu wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ fọwọ́ wọn lé ori akọmalu na fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ. 15 O si pa a; Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si fi iká rẹ̀ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na yiká, o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ, o si yà a simimọ́, lati ṣètutu fun u. 16 O si mú gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, Mose si sun u lori pẹpẹ. 17 Ṣugbọn akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, on li o fi iná sun lẹhin ibudó; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 18 O si mú àgbo ẹbọ sisun wá: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na. 19 O si pa a: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká. 20 O si kun àgbo na; Mose si sun ori rẹ̀, ati ara rẹ̀, ati ọrá na. 21 O si ṣìn ifun rẹ̀ ati itan rẹ̀ ninu omi; Mose si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ: ẹbọ sisun fun õrùn didùn ni: ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 22 O si mú àgbo keji wá, àgbo ìyasimimọ́: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na. 23 O si pa a; Mose si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀. 24 O si mú awọn ọmọ Aaroni wá, Mose si tọ́ ninu ẹ̀jẹ na si eti ọtún wọn, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká. 25 O si mú ọrá na, ati ìru ti o lọrá, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, ati itan ọtún: 26 Ati lati inu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA, o mú adidùn àkara alaiwu kan, ati adidùn àkara oloróro kan, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan, o si fi wọn sori ọrá nì, ati si itan ọtún na: 27 O si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni li ọwọ́, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀, o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. 28 Mose si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si sun wọn lori pẹpẹ li ẹbọ sisun: ìyasimimọ́ ni nwọn fun õrùn didùn: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. 29 Mose si mú igẹ̀ ẹran na, o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: nitori ipín ti Mose ni ninu àgbo ìyasimimọ́; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. 30 Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. 31 Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ. 32 Eyiti o ba si kù ninu ẹran na ati ninu àkara na ni ki ẹnyin ki o fi iná sun. 33 Ki ẹnyin ki o máṣe jade si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ni ijọ́ meje, titi ọjọ́ ìyasimimọ́ nyin yio fi pé; nitori ijọ́ meje ni a o fi yà nyin simimọ́. 34 Bi o ti ṣe li oni yi, bẹ̃li OLUWA fi aṣẹ lelẹ lati ṣe, lati ṣètutu fun nyin. 35 Nitorina ni ki ẹnyin ki o joko nibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, li ọsán ati li oru ni ijọ́ meje, ki ẹnyin ki o si ma pa aṣẹ OLUWA mọ́, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi. 36 Bẹ̃li Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo ti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ lati ọwọ́ Mose wá. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria