Lefitiku 12 - Bibeli MimọÌwẹ̀nùmọ́ Àwọn Obinrin Lẹ́yìn Ìbímọ 1 OLUWA si sọ fun Mose pe, 2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi obinrin kan ba lóyun, ti o si bi ọmọkunrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; gẹgẹ bi ọjọ́ ìyasọtọ fun ailera rẹ̀ ni ki o jẹ́ alaimọ́. 3 Ni ijọ́ kẹjọ ni ki a si kọ ọmọkunrin na nilà. 4 Ki obinrin na ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọjọ́ mẹtalelọgbọ̀n; ki o máṣe fọwọkàn ohun mimọ́ kan, bẹ̃ni ki o máṣe lọ sinu ibi mimọ́, titi ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ yio fi pé. 5 Ṣugbọn bi o ba bi ọmọbinrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ li ọsẹ̀ meji, bi ti inu ìyasọtọ rẹ̀: ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọgọta ọjọ́ o le mẹfa. 6 Nigbati ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ ba pé, fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, ki o mú ọdọ-agutan ọlọdún kan wá fun ẹbọ sisun, ati ẹiyẹle, tabi àdaba, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ ajọ: 7 Ẹniti yio ru u niwaju OLUWA, ti yio si ṣètutu fun u; on o si di mimọ́ kuro ninu isun ẹ̀jẹ rẹ̀. Eyi li ofin fun ẹniti o bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin. 8 Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá; ọkan fun ẹbọ sisun, ati ekeji fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: alufa yio si ṣètutu fun u, on o si di mimọ́. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria