Joṣua 20 - Bibeli MimọÀwọn Ìlú Ààbò 1 OLUWA si sọ fun Joṣua pe, 2 Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ yàn ilu àbo fun ara nyin, ti mo ti sọ fun nyin lati ọwọ́ Mose wa: 3 Ki apania ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan li aimọ̀ ki o le salọ sibẹ̀: nwọn o si jẹ́ àbo fun nyin lọwọ olugbẹsan ẹ̀jẹ. 4 On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé. 5 Bi olugbẹsan ẹ̀jẹ ba lepa rẹ̀, njẹ ki nwọn ki o má ṣe fi apania na lé e lọwọ; nitoriti o pa aladugbo rẹ̀ li aimọ̀, ti kò si korira rẹ̀ tẹlẹrí. 6 On o si ma gbé inu ilu na, titi yio fi duro niwaju ijọ fun idajọ, titi ikú olori alufa o wà li ọjọ́ wọnni: nigbana ni apania na yio pada, on o si wá si ilu rẹ̀, ati si ile rẹ̀, si ilu na lati ibiti o gbé ti salọ. 7 Nwọn si yàn Kedeṣi ni Galili ni ilẹ òke Naftali, ati Ṣekemu ni ilẹ òke Efraimu, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni) ni ilẹ òke Juda. 8 Ati ni ìha keji Jordani lẹba Jeriko ni ìla-õrùn, nwọn yàn Beseri li aginjù ni pẹtẹlẹ̀ ninu ẹ̀ya Reubeni, ati Ramotu ni Gileadi ninu ẹ̀ya Gadi, ati Golani ni Baṣani ninu ẹ̀ya Manasse. 9 Wọnyi ni awọn ilu ti a yàn fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo lãrin wọn, ki ẹnikẹni ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan, ki o le salọ sibẹ̀, ki o má ba si ti ọwọ́ olugbẹsan ẹ̀jẹ ku, titi on o fi duro niwaju ijọ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria