Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Joṣua 16 - Bibeli Mimọ


Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 IPÍN awọn ọmọ Josefu yọ lati Jordani lọ ni Jeriko, ni omi Jeriko ni ìha ìla-õrùn, ani aginjù, ti o gòke lati Jeriko lọ dé ilẹ òke Beti-eli;

2 O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu;

3 O si sọkalẹ ni ìha ìwọ-õrùn si àgbegbe Jafleti, dé àgbegbe Beti-horoni isalẹ, ani dé Geseri: o si yọ si okun.

4 Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn.


Efraimu

5 Àla awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn li eyi: ani àla ilẹ-iní wọn ni ìha ìla-õrùn ni Atarotu-adari, dé Beti-horoni òke;

6 Àla na si lọ si ìha ìwọ-õrùn si ìha ariwa Mikmeta; àla na si yi lọ si ìha ìla-õrùn dé Taanati-ṣilo, o si kọja lẹba rẹ̀ lọ ni ìha ìla-õrùn Janoha;

7 O si sọkalẹ lati Janoha lọ dé Atarotu, ati dé Naara, o si dé Jeriko, o si yọ si Jordani.

8 Àla na jade lọ lati Tappua si ìha ìwọ-õrùn titi dé odò Kana; o si yọ si okun. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn;

9 Pẹlu ilu ti a yàsọtọ fun awọn ọmọ Efraimu lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Manasse, gbogbo ilu na pẹlu ileto wọn.

10 Nwọn kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade: ṣugbọn awọn ara Kenaani joko lãrin Efraimu titi di oni yi, nwọn si di ẹrú lati ma sìnru.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan