Joṣua 12 - Bibeli MimọÀwọn Ọba Tí Mose Ṣẹgun 1 NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun: 2 Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni; 3 Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga: 4 Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei, 5 O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni. 6 Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse. Àwọn Ọba Tí Joṣua Ṣẹgun 7 Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn. 8 Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: 9 Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan. 10 Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan; 11 Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan; 12 Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan; 13 Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan; 14 Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan; 15 Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan; 16 Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan; 17 Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan; 18 Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan; 19 Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan; 20 Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan; 21 Ọba Taanaki, ọkan; ọba Megiddo, ọkan; 22 Ọba Kedeṣi, ọkan; ọba Jokneamu ti Karmeli, ọkan; 23 Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan; 24 Ọba Tirsa, ọkan; gbogbo awọn ọba na jẹ́ mọkanlelọgbọ̀n. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria