Jona 3 - Bibeli MimọJona Gbọ́ràn sí OLUWA Lẹ́nu 1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jona wá lẹ̃keji, wipe, 2 Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ. 3 Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi tó irin ijọ mẹta. 4 Jona si bẹrẹsi wọ inu ilu na lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wipe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bì Ninefe wo. 5 Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn. 6 Ọ̀rọ na si de ọdọ ọba Ninefe, o si dide kuro lori itẹ rẹ̀, o si bọ aṣọ igunwa rẹ̀ kuro lara rẹ̀, o si daṣọ ọ̀fọ bora, o si joko ninu ẽru. 7 O si kede rẹ̀, o si wi pe ki a là Ninefe ja nipa aṣẹ ọba, ati awọn agbagbà rẹ̀ pe, Máṣe jẹ ki enia, tabi ẹranko, ọwọ-ẹran tabi agbo-ẹran, tọ́ ohunkohun wò: má jẹ ki wọn jẹun, má jẹ ki wọn mu omi. 8 Ṣugbọn jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọ ọ̀fọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọ̀na ibi rẹ̀, ati kuro ni ìwa agbara ti o wà lọwọ wọn. 9 Tani le mọ̀ bi Ọlọrun yio yipada ki o si ronupiwada, ki o si yipada kuro ni ibinu gbigbona rẹ̀, ki awa má ṣegbe? 10 Ọlọrun si ri iṣe wọn pe nwọn yipada kuro li ọ̀na ibi wọn: Ọlọrun si ronupiwada ibi ti on ti wi pe on o ṣe si wọn; on kò si ṣe e mọ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria