Jobu 40 - Bibeli Mimọ1 OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe, 2 Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn! 3 Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe: 4 Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi. 5 Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́. 6 Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe: 7 Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́. 8 Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo? 9 Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on? 10 Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ. 11 Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ. 12 Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn. 13 Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ. 14 Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la. 15 Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu. 16 Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀. 17 On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀. 18 Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin. 19 On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ. 20 Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire. 21 O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ. 22 Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri. 23 Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀. 24 Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀? |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria