Jobu 28 - Bibeli Mimọ1 NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura. 2 Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá. 3 Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo. 4 Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia. 5 Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná. 6 Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura. 7 Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri. 8 Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí. 9 O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá. 10 O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo. 11 O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ. 12 Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye? 13 Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè. 14 Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi. 15 A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀. 16 A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri. 17 Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀. 18 A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ. 19 Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e. 20 Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? 21 A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. 22 Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. 23 Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, 24 Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun. 25 Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi. 26 Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá: 27 Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri. 28 Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye! |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria