Jobu 25 - Bibeli Mimọ1 NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe, 2 Ijọba ati ẹ̀ru mbẹ lọdọ rẹ̀, on ni iṣe ilaja ni ibi gigagiga rẹ̀. 3 Awọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ni iye bi, tabi ara tani imọlẹ rẹ̀ kò mọ́ si? 4 Eha ti ṣe ti a o fi da enia lare lọdọ Ọlọrun, tabi ẹniti a bi lati inu obinrin wá yio ha ṣe mọ́? 5 Kiyesi i, òṣupa kò si le itan imọlẹ, ani awọn ìrawọ kò mọlẹ li oju rẹ̀. 6 Ambọtori enia ti iṣe idin, ati ọmọ enia, ti iṣe kòkoro! |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria