Jobu 24 - Bibeli Mimọ1 ẼṢE bi igba-igba kò pamọ lọdọ Olodumare; ti awọn ojulumọ rẹ̀ kò ri ọjọ rẹ̀? 2 Nwọn a ṣi àmi àla ilẹ, nwọn a fi agbara ko agbo ẹran lọ, nwọn si bọ́ wọn. 3 Nwọn a si dà kẹtẹkẹtẹ alainibaba lọ, nwọn a si gba ọdá-malu opó li ohun ògo. 4 Nwọn a bì alaini kuro loju ọ̀na, awọn talaka aiye a sa pamọ́ pọ̀. 5 Kiyesi i, bi kẹtẹkẹtẹ igbẹ ninu ijù ni nwọn ijade lọ si iṣẹ wọn; nwọn a tete dide lati wá ohun ọdẹ; ijù pese onjẹ fun wọn ati fun awọn ọmọ wọn. 6 Olukuluku a si ṣa ọka onjẹ-ẹran rẹ̀ ninu oko, nwọn a si ká ọgba-ajara enia buburu. 7 Nihoho ni nwọn ma sùn laini aṣọ, ti nwọn kò ni ibora ninu otutu. 8 Ọwara ojo oke-nla si pa wọn, nwọn si lẹ̀mọ apata nitoriti kò si abo. 9 Nwọn ja ọmọ-alainibaba kuro li ẹnu-ọmu, nwọn si gbà ohun ẹ̀ri li ọwọ talaka. 10 Nwọn rìn kiri nihoho laili aṣọ, awọn ti ebi npa rẹrù ìdi-ọka. 11 Awọn ẹniti nfún ororo ninu agbala wọn, ti nwọn si ntẹ ifunti àjara, ongbẹ si ngbẹ wọn. 12 Awọn enia nkerora lati ilu wá, ọkàn awọn ẹniti o gbọgbẹ kigbe soke; sibẹ Ọlọrun kò kiyesi iwère na. 13 Awọn li o wà ninu awọn ti o kọ̀ imọlẹ, nwọn kò mọ̀ ipa ọ̀na rẹ̀, bẹni nwọn kò duro nipa ọ̀na rẹ̀. 14 Panipani a dide li afẹmọ́jumọ pa talaka ati alaini, ati li oru a di olè. 15 Oju àlagbere pẹlu duro de ofefe ọjọ, o ni, Oju ẹnikan kì yio ri mi, o si fi iboju boju rẹ̀. 16 Li òkunkun nwọn a runlẹ wọle, ti nwọn ti fi oju sọ fun ara wọn li ọsan, nwọn kò mọ̀ imọlẹ. 17 Nitoripe bi oru dudu ni owurọ̀ fun gbogbo wọn; nitoriti nwọn si mọ̀ ibẹru oru dudu. 18 O yara lọ bi ẹni loju omi; ifibu ni ipin wọn li aiye, on kò rìn lọ mọ li ọ̀na ọgba-ajara. 19 Ọdá ati õru ni imu omi ojo-didi gbẹ, bẹ̃ni isa-okú irun awọn ẹ̀lẹṣẹ. 20 Inu ibímọ yio gbagbe rẹ̀, kokoro ni yio ma fi adun jẹun lara rẹ̀, a kì yio ranti rẹ̀ mọ́; bẹ̃ni a o si ṣẹ ìwa-buburu bi ẹni ṣẹ igi. 21 Ẹniti o hù ìwa-buburu si agàn ti kò bí ri, ti kò ṣe rere si opó. 22 O fi ipá rẹ̀ fà alagbara lọ pẹlu; o dide, kò si ẹniti ẹmi rẹ̀ da loju. 23 On si fi ìwa ailewu fun u, ati ninu eyi ni a o si tì i lẹhin, oju rẹ̀ si wà ni ipa-ọna wọn. 24 A gbe wọn lekè nigba diẹ, nwọn kọja lọ, a si rẹ̀ wọn silẹ, a si mu wọn kuro li ọ̀na, bi awọn ẹlomiran, a si ke wọn kuro bi ori ṣiri itú ọkà bàbà. 25 Njẹ, bi kò ba ri bẹ̃ nisisiyi, tani yio mu mi li eké, ti yio si fi ọ̀rọ mi ṣe alainidi? |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria