Jeremiah 49 - Bibeli MimọÌdájọ́ OLUWA Lórí Amoni 1 SI awọn ọmọ Ammoni. Bayi li Oluwa wi; Israeli kò ha ni awọn ọmọkunrin? kò ha ni arole bi? nitori kini Malkomu ṣe jogun Gadi, ti awọn enia rẹ̀ si joko ni ilu rẹ̀? 2 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o mu ki a gbọ́ idagiri ogun ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni: yio si di okiti ahoro, a o si fi iná sun awọn ọmọbinrin rẹ̀; nigbana ni Israeli yio jẹ arole awọn ti o ti jẹ arole rẹ̀, li Oluwa wi. 3 Hu, iwọ Heṣboni! nitori a fi Ai ṣe ijẹ: kigbe, ẹnyin ọmọbinrin Rabba! ẹ di aṣọ-ọ̀fọ mọra, ẹ pohunrere, ki ẹ si sare soke-sodo lãrin ọgba! nitori Malkomu yio jumọ lọ si igbekun, awọn alufa rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀. 4 Ẽṣe ti iwọ fi nṣogo ninu afonifoji, afonifoji rẹ nṣan lọ, iwọ ọmọbinrin ti o gbẹkẹle iṣura rẹ, pe, tani yio tọ̀ mi wá? 5 Wò o, emi o mu ẹ̀ru wá sori rẹ, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, lati ọdọ gbogbo awọn wọnni ti o wà yi ọ kakiri; a o si le nyin, olukuluku enia tàra niwaju rẹ̀; ẹnikan kì o si kó awọn ti nsalọ jọ. 6 Ati nikẹhin emi o tun mu igbekun awọn ọmọ Ammoni pada, li Oluwa wi. Ìdájọ́ OLUWA lórí Edomu 7 Si Edomu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Kò ha si ọgbọ́n mọ ni Temani? a ha ke imọran kuro lọdọ oloye? ọgbọ́n wọn ha danu bi? 8 Ẹ sa, ẹ yipada, ẹ ṣe ibi jijin lati ma gbe ẹnyin olugbe Dedani; nitori emi o mu wahala Esau wá sori rẹ̀, àkoko ti emi o bẹ̀ ẹ wò. 9 Bi awọn aka-eso ba tọ̀ ọ wá, nwọn kì o ha kù ẽṣẹ́ eso ajara silẹ? bi awọn ole ba wá li oru, nwọn kì o ha parun titi yio fi tẹ́ wọn lọrùn. 10 Nitori emi ti tú Esau ni ihoho, emi ti fi ibi ikọkọ rẹ̀ han, on kì o si le fi ara rẹ̀ pamọ; iru-ọmọ rẹ̀ di ijẹ, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn aladugbo rẹ̀, nwọn kò sí mọ́. 11 Fi awọn ọmọ alainibaba rẹ silẹ, emi o si pa wọn mọ lãye; ati ki awọn opó rẹ ki o gbẹkẹle mi. 12 Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, awọn ẹniti kò jẹbi, lati mu ninu ago, ni yio mu u lõtọ: iwọ o ha si lọ li alaijiya? iwọ kì yio lọ li alaijiya, nitori lõtọ iwọ o mu u. 13 Nitori emi ti fi ara mi bura, li Oluwa wi pe: Bosra yio di ahoro, ẹ̀gan, idahoro, ati egún; ati gbogbo ilu rẹ̀ ni yio di ahoro lailai. 14 Ni gbigbọ́ emi ti gbọ́ iró lati ọdọ Oluwa wá, a si ran ikọ̀ si awọn orilẹ-ède pe, ẹ kó ara nyin jọ, ẹ wá sori rẹ̀, ẹ si dide lati jagun. 15 Nitori, wò o, emi o ṣe ọ ni ẹni-kekere lãrin awọn orilẹ-ède, ẹni-ẹgan lãrin awọn enia. 16 Ibanilẹ̀ru rẹ ti tan ọ jẹ, igberaga ọkàn rẹ, nitori iwọ ngbe palapala okuta, ti o joko li ori oke, bi iwọ tilẹ kọ́ itẹ́ rẹ ga gẹgẹ bi idì, sibẹ emi o mu ọ sọkalẹ lati ibẹ wá, li Oluwa wi. 17 Edomu yio si di ahoro: olukuluku ẹniti o ba rekọja rẹ̀, yio dãmu, yio si rẹrin si gbogbo ipọnju rẹ̀. 18 Gẹgẹ bi ni ibiṣubu Sodomu ati Gomorra ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; ẹnikan kì yio gbe ibẹ mọ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀. 19 Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi? 20 Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa ti o ti gbà si Edomu; ati èro rẹ̀ ti o ti gba si awọn olugbe Temani pe, Lõtọ awọn ẹniti o kere julọ ninu agbo-ẹran yio wọ́ wọn kiri, lõtọ nwọn o sọ buka wọn di ahoro lori wọn. 21 Ilẹ o mì nipa ariwo iṣubu wọn, ariwo! a gbọ́ ohùn igbe rẹ̀ li Okun-pupa. 22 Wò o, yio goke wá yio si fò gẹgẹ bi idì, yio si nà iyẹ rẹ̀ sori Bosra: ati li ọjọ na ni ọkàn awọn alagbara ọkunrin Edomu yio dabi ọkàn obinrin ni irọbi. Ìdájọ́ OLUWA lórí Damasku 23 Si Damasku. Oju tì Hamati, ati Arpadi: nitori nwọn ti gbọ́ ìhin buburu: aiya ja wọn; idãmu wà lẹba okun; nwọn kò le ri isimi. 24 Damasku di alailera, o yi ara rẹ̀ pada lati sa, iwarìri si dì i mu: ẹ̀dun ati irora ti dì i mu, gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi. 25 Bawo ni a kò ṣe fi ilu iyìn silẹ, ilu ayọ̀ mi! 26 Nitorina awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ọkunrin ogun ni a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 27 Emi o si da iná ni odi Damasku, yio si jo ãfin Benhadadi run. A Óo Rẹ Moabu sílẹ̀ 28 Si Kedari, ati si ijọba Hasori, ti Nebukadnessari ọba Babeli, kó: Bayi li Oluwa wi; Dide, goke lọ si Kedari, ki ẹ si pa awọn ọkunrin ìla-õrùn run. 29 Agọ wọn ati agbo-ẹran wọn ni nwọn o kó lọ: nwọn o mu aṣọ agọ wọn fun ara wọn, ati gbogbo ohun-èlo wọn, ati ibakasiẹ wọn; nwọn o si kigbe sori wọn pe, Ẹ̀ru yikakiri! 30 Sa, yara salọ, fi ara pamọ si ibi jijìn, ẹnyin olugbe Hasori, li Oluwa wi; nitori Nebukadnessari ọba Babeli, ti gbìmọ kan si nyin, o si ti gba èro kan si nyin. 31 Dide, goke lọ sọdọ orilẹ-ède kan ti o wà ni irọra, ti o ngbe li ailewu, li Oluwa wi, ti kò ni ilẹkun ẹnu-bode tabi ikere; ti ngbe fun ara rẹ̀. 32 Ibakasiẹ wọn yio si di ikogun, ati ọ̀pọlọpọ ẹran-ọ̀sin wọn yio di ijẹ: emi o si tú awọn ti nda òṣu ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ; emi o si mu wahala wọn de lati iha gbogbo, li Oluwa wi. 33 Hasori yio di ibugbe fun ọ̀wawa, ahoro titi lai: kì o si ẹnikan ti yio joko nibẹ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀. Ìdájọ́ OLUWA lórí Elamu 34 Ọ̀rọ Oluwa ti o tọ Jeremiah, woli, wá si Elamu, ni ibẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, wipe: 35 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o ṣẹ́ ọrun Elamu, ti iṣe olori agbara wọn. 36 Ati sori Elamu ni emi o mu afẹfẹ mẹrin lati igun mẹrẹrin ọrun wá, emi o si tú wọn ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ wọnni, kì o si sí orilẹ-ède kan, nibiti awọn ãsá Elamu kì yio de. 37 Nitori emi o mu Elamu warìri niwaju awọn ọta wọn, ati niwaju awọn ti nwá ẹmi wọn: emi o si mu ibi wá sori wọn, ani ibinu gbigbona mi, li Oluwa wi; emi o si rán idà tẹle wọn, titi emi o fi run wọn. 38 Emi o si gbe itẹ mi kalẹ ni Elamu, emi o si pa ọba ati awọn ijoye run kuro nibẹ, li Oluwa wi. 39 Ṣugbọn yio si ṣe, ni ikẹhin ọjọ, emi o tun mu igbèkun Elamu pada, li Oluwa wi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria