Isaiah 63 - Bibeli MimọÌròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè 1 TANI eleyi ti o ti Edomu wá, ti on ti aṣọ arẹpọ́n lati Bosra wá? eyi ti o li ogo ninu aṣọ rẹ̀, ti o nyan ninu titobi agbara rẹ̀? Emi ni ẹniti nsọ̀rọ li ododo, ti o ni ipá lati gbala. 2 Nitori kini aṣọ rẹ fi pọ́n, ti aṣọ rẹ wọnni fi dabi ẹniti ntẹ̀ ohun-èlo ifunti waini? 3 Emi nikan ti tẹ̀ ohun-elò ifunti waini; ati ninu awọn enia, ẹnikan kò pẹlu mi: nitori emi tẹ̀ wọn ninu ibinu mi, mo si tẹ̀ wọn mọlẹ ninu irunú mi; ẹ̀jẹ wọn si ta si aṣọ mi, mo si ṣe gbogbo ẹ̀wu mi ni abawọ́n. 4 Nitori ọjọ ẹsan mbẹ li aiya mi, ọdun awọn ẹni-irapada mi ti de. 5 Mo si wò, kò si si oluranlọwọ; ẹnu si yà mi pe kò si olugbéro; nitorina apa ti emi tikalami mu igbala wá sọdọ mi; ati irunú mi, on li o gbe mi ro. 6 Emi si tẹ̀ awọn enia mọlẹ ninu ibinu mi, mo si mu wọn mu yó ninu irunú mi, mo si mu ipa wọn sọkalẹ si ilẹ. Oore OLUWA sí Israẹli 7 Emi o sọ ti iṣeun ifẹ Oluwa, iyìn Oluwa gẹgẹ bi gbogbo eyiti Oluwa ti fi fun wa, ati ti ore nla si ile Israeli, ti o ti fi fun wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀, ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ iṣeun ifẹ rẹ̀. 8 On si wipe, Lõtọ enia mi ni nwọn, awọn ọmọ ti kì iṣeke: on si di Olugbala wọn. 9 Ninu gbogbo ipọnju wọn, oju a pọn ọ, angeli iwaju rẹ̀ si gbà wọn: ninu ifẹ rẹ̀ ati suru rẹ̀ li o rà wọn pada; o si gbe wọn, o si rù wọn ni gbogbo ọjọ igbani. 10 Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ, nwọn si bi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ ninu; nitorina li o ṣe pada di ọta wọn, on tikalarẹ̀ si ba wọn ja. 11 Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà? 12 Ti o fi ọwọ́ ọtun Mose dà wọn, pẹlu apá rẹ̀ ti o logo, ti o npin omi meji niwaju wọn, lati ṣe orukọ aiyeraiye fun ara rẹ̀? 13 Ti o mu wọn là ibú ja, bi ẹṣin li aginjù, ki nwọn ki o má ba kọsẹ? 14 Gẹgẹ bi ẹran ti isọ̀kalẹ lọ si afonifoji, bẹ̃ni Ẹmi Oluwa mu u simi: bẹ̃ni iwọ tọ́ awọn enia rẹ, lati ṣe orukọ ti o li ogo fun ara rẹ. Adura fún Àánú ati Ìrànlọ́wọ́ 15 Wò ilẹ lati ọrun wá, ki o si kiyesi lati ibugbe ìwa mimọ́ rẹ ati ogo rẹ wá: nibo ni itara rẹ ati agbara rẹ, ọ̀pọlọpọ iyanu rẹ, ati ãnu rẹ sọdọ mi gbe wà? a ha da wọn duro bi? 16 Laiṣiyemeji iwọ ni baba wa, bi Abrahamu tilẹ ṣe alaimọ̀ wa, ti Israeli kò si jẹwọ wa: iwọ Oluwa, ni baba wa, Olurapada wa; lati aiyeraiye ni orukọ rẹ. 17 Oluwa, nitori kili o ṣe mu wa ṣina kuro li ọ̀na rẹ, ti o si sọ ọkàn wa di lile kuro ninu ẹ̀ru rẹ? Yipada nitori awọn iranṣẹ rẹ, awọn ẹya ilẹ ini rẹ. 18 Awọn enia mimọ́ rẹ ti ni i, ni igba diẹ: awọn ọta wa ti tẹ̀ ibi mimọ́ rẹ mọlẹ. 19 Tirẹ li awa: lati lailai iwọ kò jọba lori wọn, a kò pè orukọ rẹ mọ wọn. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria