Isaiah 39 - Bibeli MimọỌba Babiloni kọ ìwé kí Hesekaya 1 LI akoko na ni Merodaki-baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitori o ti gbọ́ pe o ti ṣaisàn, o si ti sàn. 2 Inu Hesekiah si dùn si wọn, o si fi ile iṣura hàn wọn, fadaka, ati wura, ati nkan olõrun didùn, ati ikunra iyebiye, ati ile gbogbo ìhamọra rẹ̀, ati ohun gbogbo ti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si si nkankan ti Hesekiah kò fi hàn wọn ninu ile rẹ̀, tabi ni ijọba rẹ̀. 3 Nigbana ni wolĩ Isaiah wá sọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kini awọn ọkunrin wọnyi wi? ati lati ibo ni nwọn ti wá sọdọ rẹ? Hesekiah si wi pe, Lati ilẹ jijin ni nwọn ti wá sọdọ mi, ani lati Babiloni. 4 O si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn pe, Ohun gbogbo ti o wà ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkankan ti emi kò fi hàn wọn ninu iṣura mi. 5 Nigbana ni Isaiah wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun: 6 Kiyesi i, ọjọ na dé, ti a o kó ohun gbogbo ti o wà ni ile rẹ, ati ohun ti awọn baba rẹ ti kojọ titi di oni, lọ si Babiloni: kò si nkankan ti yio kù, li Oluwa wi. 7 Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ: nwọn o si jẹ́ iwẹ̀fa ni ãfin ọba Babiloni. 8 Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere ni ọ̀rọ Oluwa ti iwọ ti sọ. O si wi pẹlu pe, Alafia ati otitọ́ yio sa wà li ọjọ mi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria