Isaiah 38 - Bibeli MimọÀìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀ 1 LI ọjọ wọnni Hesekiah ṣaisàn de oju ikú. Woli Isaiah ọmọ Amosi si wá sọdọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Bayi ni Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́: nitori iwọ o kú, o ki yio si yè. 2 Nigbana ni Hesekiah yi oju rẹ̀ si ogiri, o si gbadura si Oluwa. 3 O si wipe, Nisisiyi, Oluwa, mo bẹ̀ ọ, ranti bi mo ti rìn niwaju rẹ li otitọ ati pẹlu aiya pipé, ati bi mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún pẹrẹ̀pẹrẹ̀. 4 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Isaiah wá, wipe, 5 Lọ, si wi fun Hesekiah pe, Bayi ni Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, mo ti gbọ́ adura rẹ, mo ti ri omije rẹ: kiyesi i emi o fi ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ. 6 Emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria: emi o si dãbò bò ilu yi. 7 Eyi yio sì jẹ àmi fun ọ lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti o ti sọ; 8 Kiyesi i, emi o tún mu ìwọn òjiji ti o ti sọkalẹ lara agogo-õrùn Ahasi pada ni ìwọn mẹwa. Bẹ̃ni õrun pada ni ìwọn mẹwa ninu ìwọn ti o ti sọkalẹ. Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ 9 Iwe Hesekiah ọba Juda, nigbati o fi ṣaisàn, ti o si sàn ninu aisàn rẹ̀: 10 Mo ni, ni ìke-kuro ọjọ mi, emi o lọ si ẹnu-ọnà isà-okú; a dù mi ni iyokù ọdun mi. 11 Mo ni, emi kì yio ri Oluwa, ani Oluwa, ni ilẹ alãyè: emi kì yio ri enia mọ lãrin awọn ti ngbé ibi idakẹ. 12 Ọjọ ori mi lọ, a si ṣi i kuro lọdọ mi bi àgọ olùṣọ agutan: mo ti ké ẹmi mi kuro bi ahunṣọ: yio ké mi kuro bi fọ́nran-òwu tinrin: lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi. 13 Mo ṣirò titi di òwurọ, pe, bi kiniun, bẹ̃ni yio fọ́ gbogbo egungun mi; lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi. 14 Bi akọ̀ tabi alapandẹ̀dẹ, bẹ̃ni mo dún; mo kãnu bi oriri: ãrẹ̀ mu oju mi fun iwòke: Oluwa, ara nni mi: ṣe onigbọwọ mi. 15 Kili emi o wi? o ti sọ fun mi, on tikalarẹ̀ si ti ṣe e: emi o ma lọ jẹjẹ fun gbogbo ọdun mi ni kikorò ọkàn mi. 16 Oluwa, nipa nkan wọnyi li enia ima wà, ati ni gbogbo nkan wọnyi ni iye ẹmi mi: bẹ̃ni iwọ o mu mi lara dá, iwọ o si mu mi yè. 17 Kiyesi i, mo ti ni ikorò nla nipò alafia: ṣugbọn iwọ ti fẹ́ ọkàn mi lati ihò idibàjẹ wá: nitori iwọ ti gbe gbogbo ẹ̀ṣẹ mi si ẹ̀hin rẹ. 18 Nitori ibojì kò le yìn ọ, ikú kò le fiyìn fun ọ: awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò kò le ni irèti otitọ rẹ. 19 Alãyè, alãyè, on ni yio yìn ọ, bi mo ti nṣe loni yi: baba yio fi otitọ rẹ hàn fun awọn ọmọ. 20 Oluwa mura tan lati gbà mi: nitorina a o kọ orin mi lara dùrù olokùn, ni gbogbo ọjọ aiye wa ni ile Oluwa. 21 Nitori Isaiah ti wipe, Ki nwọn mu ìṣu ọ̀pọtọ́, ki a si fi ṣán õwo na, yio si sàn. 22 Hesekiah pẹlu ti wipe, Kili àmi na pe emi o goke lọ si ile Oluwa? |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria