Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Isaiah 35 - Bibeli Mimọ


Ọ̀nà Ìwà Mímọ́

1 AGINJU ati ilẹ gbigbẹ yio yọ̀ fun wọn; ijù yio yọ̀, yio si tanna bi lili.

2 Ni titanna yio tanna; yio si yọ̀ ani pẹlu ayọ̀ ati orin: ogo Lebanoni li a o fi fun u, ẹwà Karmeli on Ṣaroni; nwọn o ri ogo Oluwa, ati ẹwà Ọlọrun wa.

3 Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun.

4 Ẹ sọ fun awọn alailaiyà pe, ẹ tujuka, ẹ má bẹ̀ru: wò o, Ọlọrun nyin o wá ti on ti ẹsan, Ọlọrun ti on ti igbẹsan; on o wá, yio si gbà nyin.

5 Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi.

6 Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.

7 Ilẹ yíyan yio si di àbata, ati ilẹ ongbẹ yio di isun omi; ni ibugbé awọn dragoni, nibiti olukuluku dubulẹ, ni o jẹ ọgbà fun ẽsú on iyè.

8 Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i.

9 Kiniun kì yio si nibẹ, bẹ̃ni ẹranko buburu kì yio gùn u, a kì yio ri i nibẹ; ṣugbọn awọn ti a ràpada ni yio ma rìn nibẹ:

10 Awọn ẹni-iràpada Oluwa yio padà, nwọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ̀ ati inu didùn gbà, ikãnu on imí-ẹ̀dùn yio si fò lọ.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan