Ìfihàn 4 - Bibeli MimọÌsìn ní Ọ̀run 1 LẸHIN nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan ṣí silẹ li ọrun: ohùn kini ti mo gbọ bi ohùn ipè ti mba mi sọ̀rọ, ti o wipe, Goke wa ìhin, emi o si fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn ọ. 2 Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na. 3 Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo. 4 Yi itẹ́ na ká si ni itẹ́ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ́ na mo ri awọn àgba mẹrinlelogun joko, ti a wọ̀ li aṣọ àlà; ade wura si wà li ori wọn. 5 Ati lati ibi itẹ́ na ni mànamána ati ãrá ati ohùn ti jade wá: fitila iná meje si ntàn nibẹ̀ niwaju itẹ́ na, ti iṣe Ẹmi meje ti Ọlọrun. 6 Ati niwaju itẹ́ na si ni okun bi digí, o dabi kristali: li arin itẹ́ na, ati yi itẹ́ na ká, li ẹda alãye mẹrin ti o kún fun oju niwaju ati lẹhin. 7 Ẹda ikini si dabi kiniun, ẹda keji si dabi ọmọ malu, ẹda kẹta si ni oju bi ti enia, ẹda kẹrin si dabi idì ti nfò. 8 Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ́ mẹfa, kun fun oju yika ati ninu: nwọn kò si simi li ọsán ati li oru, wipe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, Oluwa Ọlọrun Olodumare, ti o ti wà, ti o si mbẹ, ti o si mbọ̀wá. 9 Nigbati awọn ẹda alãye na ba si fi ogo ati ọlá ati ọpẹ́ fun ẹniti o joko lori itẹ́, ti o mbẹ lãye lai ati lailai, 10 Awọn àgba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹniti o joko lori itẹ́, nwọn a si tẹriba fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai, nwọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ́ na, wipe, 11 Oluwa, iwọ li o yẹ lati gbà ogo ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni nwọn fi wà ti a si dá wọn. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria