Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Hosea 6 - Bibeli Mimọ


Àwọn Eniyan náà Ṣe Ìrònúpìwàdà Èké

1 Ẹ wá, ẹ jẹ ki a yipadà si Oluwa: nitori o ti fà wa ya, on o si mu wa lara da; o ti lù wa, yio si tun wa dì.

2 Lẹhìn ijọ meji, yio tún wa jí: ni ijọ kẹta yio ji wa dide, awa o si wà lãyè niwaju rẹ̀.

3 Nigbana li awa o mọ̀, bi a ba tẹramọ́ ati mọ̀ Oluwa: ati pèse ijadelọ rẹ̀ bi owùrọ: on o si tọ̀ wa wá bi ojò: bi arọ̀kuro ati akọrọ̀ òjo si ilẹ.

4 Efraimu, kili emi o ṣe si ọ? Juda, kili emi o ṣe si ọ? nitori ore nyin dàbi ikuku owurọ̀, ati bi ìri kùtukùtu ti o kọja lọ.

5 Nitorina ni mo ṣe fi ãké ké wọn lati ọwọ awọn woli; mo ti fi ọ̀rọ ẹnu mi pa wọn: ki idajọ rẹ le ri bi imọlẹ ti o jade lọ.

6 Nitori ãnu ni mo fẹ́, ki iṣe ẹbọ; ati ìmọ Ọlọrun jù ọrẹ-ẹbọ sisun lọ.

7 Ṣugbọn bi Adamu nwọn ti dá majẹmu kọja: nibẹ̀ ni nwọn ti ṣẹ̀tan si mi.

8 Gileadi ni ilu awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ, a si ti fi ẹ̀jẹ bà a jẹ.

9 Ati gẹgẹ bi ọwọ́ olè iti lùmọ dè enia, bẹ̃ni ẹgbẹ́ awọn alufa fohùnṣọ̀kan lati pania li ọ̀na: nitori nwọn dá ẹ̀ṣẹ nla.

10 Mo ti ri ohun buburu kan ni ile Israeli: agbère Efraimu wà nibẹ̀, Israeli ti bajẹ.

11 Iwọ Juda pẹlu, on ti gbe ikorè kalẹ fun ọ, nigbati mo ba yi igbekun awọn enia mi padà.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan