Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Hosea 14 - Bibeli Mimọ


Ẹ̀bẹ̀ Hosea fún Israẹli

1 ISRAELI, yipadà si Oluwa Ọlọrun rẹ, nitori iwọ ti ṣubu ninu aiṣedẽde rẹ.

2 Mu ọ̀rọ pẹlu nyin, ẹ si yipadà si Oluwa: ẹ wi fun u pe, Mu aiṣedẽde gbogbo kuro, si fi ore-ọfẹ gbà wa: bẹ̃ni awa o fi ọmọ malu ète wa san a fun ọ.

3 Assuru kì yio gbà wa; awa kì yio gùn ẹṣin: bẹ̃ni awa kì yio tun wi mọ fun iṣẹ ọwọ́ wa pe, Ẹnyin li ọlọrun wa: nitori lọdọ rẹ ni alainibaba gbe ri ãnu.


OLUWA Ṣèlérí Ìgbé-Ayé Titun fún Israẹli

4 Emi o wo ifàsẹhìn wọn sàn, emi o fẹ wọn lọfẹ: nitori ibinu mi yí kuro lọdọ rẹ̀.

5 Emi o dabi ìri si Israeli: on o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rẹ̀ bi Lebanoni.

6 Ẹka rẹ̀ yio tàn, ẹwà rẹ̀ yio si dabi igi olifi, ati õrùn rẹ̀ bi Lebanoni.

7 Awọn ti o ngbe abẹ ojiji rẹ̀ yio padà wá; nwọn o sọji bi ọkà: nwọn o si tanná bi àjara: õrun rẹ̀ yio dabi ọti-waini ti Lebanoni.

8 Efraimu yio wipe, Kili emi ni fi òriṣa ṣe mọ? Emi ti gbọ́, mo si ti kiyesi i: emi dabi igi firi tutù. Lati ọdọ mi li a ti ri èso rẹ.


Ọ̀rọ̀ Ìparí

9 Tali o gbọ́n, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ̀ wọn? nitori ọ̀na Oluwa tọ́, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan