Heberu 7 - Bibeli MimọIrú Alufaa tí Mẹlikisẹdẹki Jẹ́ 1 NITORI Melkisedeki yi, ọba Salemu, alufa Ọlọrun Ọgá-ogo, ẹniti o pade Abrahamu bi o ti npada lati ibi pipa awọn ọba bọ̀, ti o si sure fun u; 2 Ẹniti Abrahamu si pin idamẹwa ohun gbogbo fun; li ọna ekini ni itumọ rẹ̀ ọba ododo, ati lẹhinna pẹlu ọba Salemu, ti iṣe ọba alafia; 3 Laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bẹ̃ni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye; ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun; o wà li alufa titi. 4 Njẹ ẹ gbà a rò bi ọkunrin yi ti pọ̀ to, ẹniti Abrahamu baba nla fi idamẹwa ninu awọn aṣayan ikogun fun. 5 Ati nitõtọ awọn ti iṣe ọmọ Lefi, ti o gbà oyè alufa, nwọn ni aṣẹ lati mã gbà idamẹwa lọwọ awọn enia gẹgẹ bi ofin, eyini ni, lọwọ awọn arakunrin wọn, bi o tilẹ ti jẹ pe, nwọn ti inu Abrahamu jade. 6 Ṣugbọn on ẹniti a kò tilẹ pitan iran rẹ̀ lati ọdọ wọn wá, ti gbà idamẹwa lọwọ Abrahamu, o si ti sure fun ẹniti o gbà ileri. 7 Ati li aisijiyan rara ẹniti kò to ẹni li ã sure fun lati ọdọ ẹniti o jù ni. 8 Ati nihin, awọn ẹni kikú gbà idamẹwa; ṣugbọn nibẹ̀, ẹniti a jẹri rẹ̀ pe o mbẹ lãye. 9 Ati bi a ti le wi, Lefi papa ti ngbà idamẹwa, ti san idamẹwa nipasẹ Abrahamu. 10 Nitori o sá si mbẹ ni inu baba rẹ̀, nigbati Melkisedeki pade rẹ̀. 11 Njẹ ibaṣepe pipé mbẹ nipa oyè alufa Lefi, (nitoripe labẹ rẹ̀ li awọn enia gbà ofin), kili o si tún kù mọ́ ti alufa miran iba fi dide nipa ẹsẹ Melkisedeki, ti a kò si wipe nipa ẹsẹ Aaroni? 12 Nitoripe bi a ti pàrọ oyè alufa, a kò si le ṣai pàrọ ofin. 13 Nitori ẹniti a nsọ̀rọ nkan wọnyi nipa rẹ̀ jẹ ẹ̀ya miran, lati inu eyiti ẹnikẹni koi jọsin ri nibi pẹpẹ. 14 Nitori o han gbangba pe lati inu ẹ̀ya Juda ni Oluwa wa ti dide; nipa ẹ̀ya ti Mose kò sọ ohunkohun niti awọn alufa. Oyè Alufaa Titun, Gẹ́gẹ́ Bíi ti Mẹlikisẹdẹki 15 O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki, 16 Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin. 17 Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. 18 Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀. 19 (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun. 20 Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni. 21 (Nitori a ti fi wọn jẹ alufa laisi ibura, nipa ẹniti o wi fun u pe, Oluwa bura, kì yio si ronupiwada, Iwọ ni alufa kan titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki:) 22 Niwọn bẹ̃ ni Jesu ti di onigbọ̀wọ́ majẹmu ti o dara jù. 23 Ati nitõtọ awọn pupọ̀ li a ti fi jẹ alufa, nitori nwọn kò le wà titi nitori ikú: 24 Ṣugbọn on, nitoriti o wà titi lai, o ni oyè alufa ti a kò le rọ̀ nipò. 25 Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn. 26 Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ; 27 Ẹniti kò ni lati mã kọ́ rubọ lojojumọ, bi awọn olori alufa wọnni, fun ẹ̀ṣẹ ti ara rẹ̀ na, ati lẹhinna fun ti awọn enia: nitori eyi li o ti ṣe lẹ̃kanṣoṣo, nigbati o fi ara rẹ̀ rubọ. 28 Nitoripe ofin a mã fi awọn enia ti o ni ailera jẹ olori alufa; ṣugbọn ọ̀rọ ti ibura, ti a ṣe lẹhin ofin, o fi Ọmọ jẹ, ẹniti a sọ di pipé titi lai. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria