Gẹnẹsisi 20 - Bibeli MimọAbrahamu ati Abimeleki 1 ABRAHAMU si ṣí lati ibẹ̀ lọ si ilẹ ìha gusù, o si joko li agbedemeji Kadeṣi on Ṣuri; o si ṣe atipo ni Gerari. 2 Abrahamu si wi niti Sara aya rẹ̀ pe, Arabinrin mi ni: Abimeleki ọba Gerari si ranṣẹ, o si mu Sara. 3 Ṣugbọn Ọlọrun tọ̀ Abimeleki wá li ojuran li oru, o si wi fun u pe, kiyesi i, okú ni iwọ, nitori obinrin ti iwọ mu nì; nitori aya ọkunrin kan ni iṣe. 4 Ṣugbọn Abimeleki kò sunmọ ọ: o si wipe, OLUWA, iwọ o run orilẹ-ède olododo pẹlu? 5 On kọ ló ha wi fun mi pe arabinrin mi ni iṣe? on, obinrin tikalarẹ̀ si wipe, arakunrin mi ni: li otitọ inu ati alaiṣẹ̀ ọwọ́ mi, ni mo fi ṣe eyi. 6 Ọlọrun si wi fun u li ojuran pe, Bẹ̃ni, emi mọ̀ pe li otitọ inu rẹ ni iwọ ṣe eyi; nitorina li emi si ṣe dá ọ duro ki o má ba ṣẹ̀ mi: nitorina li emi kò ṣe jẹ ki iwọ ki o fọwọkàn a. 7 Njẹ nitori na mu aya ọkunrin na pada fun u; woli li on sa iṣe, on o si gbadura fun ọ, iwọ o si yè: bi iwọ kò ba si mu u pada, ki iwọ ki o mọ̀ pe, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo ẹniti o jẹ tirẹ. 8 Nitorina Abimeleki dide ni kutukutu owurọ̀, o si pè gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si wi gbogbo nkan wọnyi li eti wọn: ẹ̀ru si bà awọn enia na gidigidi. 9 Nigbana li Abimeleki pè Abrahamu, o si wi fun u pe, Kili o ṣe si wa yi? ẹ̀ṣẹ kini mo ṣẹ̀ ọ, ti iwọ fi mu ẹ̀ṣẹ nla wá si ori mi, ati si ori ijọba mi? iwọ hùwa si mi ti a ki ba hù. 10 Abimeleki si wi fun Abrahamu pe, Kini iwọ ri, ti iwọ fi ṣe nkan yi? 11 Abrahamu si wipe, Nitoriti mo rò pe, nitõtọ ẹ̀ru Ọlọrun kò sí nihinyi; nwọn o si pa mi nitori aya mi. 12 Ati pẹlupẹlu nitõtọ arabinrin mi ni iṣe, ọmọbinrin baba mi ni, ṣugbọn ki iṣe ọmọbinrin iya mi; o si di aya mi. 13 O si ṣe nigbati Ọlọrun mu mi rìn kiri lati ile baba mi wá, on ni mo wi fun u pe, eyi ni ore rẹ ti iwọ o ma ṣe fun mi; nibikibi ti awa o gbé de, ma wi nipa ti emi pe, arakunrin mi li on. 14 Abimeleki si mu agutan, ati akọmalu, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, o si fi wọn fun Abrahamu, o si mu Sara, aya rẹ̀, pada fun u. 15 Abimeleki si wipe, Kiyesi i, ilẹ mi niyi niwaju rẹ: joko nibiti o wù ọ. 16 O si wi fun Sara pe, Kiyesi i, mo fi ẹgbẹrun ìwọn fadaka fun arakunrin rẹ: kiyesi i, on ni ibojú fun ọ fun gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ, ati niwaju gbogbo awọn ẹlomiran li a da ọ lare. 17 Abrahamu si gbadura si Ọlọrun: Ọlọrun si mu Abimeleki li ara dá, ati aya rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin-ọdọ rẹ̀; nwọn si bimọ. 18 Nitori OLUWA ti sé inu awọn ara ile Abimeleki pinpin, nitori ti Sara, aya Abrahamu. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria