Filemoni 1 - Bibeli Mimọ1 PAULU, onde Kristi Jesu, ati Timotiu arakunrin wa, si Filemoni olufẹ ati alabaṣiṣẹ wa ọwọn, 2 Ati si Affia arabinrin wa, ati si Arkippu ọmọ-ogun ẹgbẹ wa, ati si ìjọ inu ile rẹ: 3 Ore-ọfẹ, ati alafia sí nyin, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa. Ìfẹ́ ati Igbagbọ Tí Filemoni Ní 4 Emi ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo, emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, 5 Bi mo ti ngbọ́ ti ifẹ rẹ ati igbagbọ́ ti iwọ ni si Jesu Oluwa, ati si gbogbo awọn enia mimọ́; 6 Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi. 7 Emi sá ni ayọ̀ pupọ ati itunu nitori ifẹ rẹ, nitoriti a tù ọkàn awọn enia mimọ́ lara lati ọwọ́ rẹ wá, arakunrin. Ẹ̀bẹ̀ fún Onisimu 8 Nitorina, bi mo tilẹ ni igboiya pupọ̀ ninu Kristi lati paṣẹ ohun ti o yẹ fun ọ, 9 Ṣugbọn nitori ifẹ emi kuku bẹ̀bẹ, iru ẹni bi emi Paulu arugbo, ati nisisiyi ondè Kristi Jesu pẹlu. 10 Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu: 11 Nigbakan rí ẹniti o jẹ alailere fun ọ, ṣugbọn nisisiyi o lere fun ọ ati fun mi: 12 Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi: 13 Ẹniti emi iba fẹ daduro pẹlu mi, ki o le mã ṣe iranṣẹ fun mi nipo rẹ ninu ìde ihinrere: 14 Ṣugbọn li aimọ̀ inu rẹ emi kò fẹ ṣe ohun kan; ki ore rẹ ki o má ba dabi afiyanjuṣe, bikoṣe tifẹtifẹ. 15 Nitori boya idi rẹ̀ li eyi ti o fi kuro lọdọ rẹ fun igba diẹ, ki iwọ ki o ba le ni i titi lai; 16 Kì iṣe bi ẹrú mọ, ṣugbọn o jù ẹrú lọ, arakunrin olufẹ, papa fun mi, melomelo jubẹ̃lọ fun ọ, nipa ti ara ati nipa ti Oluwa. 17 Nitorina bi iwọ ba kà mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gbà a bi emi tikarami. 18 Ṣugbọn bi o ba ti ṣẹ̀ ọ rara, tabi ti o jẹ ọ nigbese kan, kà a si mi lọrùn. 19 Emi Paulu li o fi ọwọ́ ara mi kọ ọ, emi ó san a pada: ki emi má sọ fun ọ, bi o ti jẹ mi nigbese ara rẹ pẹlu. 20 Nitõtọ, arakunrin, jẹ ki emi ki o ni ayọ̀ rẹ ninu Oluwa: tù ọkan mi lara ninu Kristi. 21 Bi mo ti ni igbẹkẹle ni igbọràn rẹ ni mo fi kọwe si ọ: nitori mo mọ̀ pe, iwọ ó tilẹ ṣe jù bi mo ti wi lọ. 22 Ati pẹlu, pese ìbuwọ̀ silẹ dè mi; nitori mo gbẹkẹle pe nipa adura nyin, a ó fi mi fun nyin. Ìdágbére 23 Epafra, ondè ẹlẹgbẹ mi ninu Kristi Jesu kí ọ; 24 Marku, Aristarku, Dema, Luku, awọn olubaṣiṣẹ mi kí ọ pẹlu. 25 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria