Esteri 10 - Bibeli MimọTítóbi Ahasu-erusi ati Modekai 1 AHASWERUSI ọba si fi owo ọba le ilẹ fun gbogbo ilẹ, ati gbogbo erekùṣu okun. 2 Ati gbogbo iṣe agbara rẹ̀, ati ti ipa rẹ̀, ati ìrohin titobi Mordekai, bi ọba ti sọ ọ di nla, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Media ati Persia? 3 Nitori Mordekai ara Juda li o ṣe igbakeji Ahaswerusi ọba, o si tobi ninu awọn Ju, o si ṣe itẹwọgbà lọdọ ọ̀pọlọpọ ninu awọn arakunrin rẹ̀, o nwá ire awọn enia rẹ̀, o si nsọ̀rọ alafia fun gbogbo awọn iru-ọmọ rẹ̀. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria