Ẹk. Jer 2 - Bibeli MimọÌyà Tí OLUWA Fi Jẹ Jerusalẹmu 1 BAWO li Oluwa ti fi awọsanma bo ọmọbinrin Sioni ni ibinu rẹ̀! ti o sọ ẹwa Israeli kalẹ lati oke ọrun wá si ilẹ, ti kò si ranti apoti-itisẹ rẹ̀ li ọjọ ibinu rẹ̀! 2 Oluwa ti gbe gbogbo ibugbe Jakobu mì, kò si da a si: o ti wó ilu-odi ọmọbinrin Juda lulẹ, ninu irunu rẹ̀ o ti lù wọn bolẹ: o ti sọ ijọba na ati awọn ijoye rẹ̀ di alaimọ́. 3 O ti ke gbogbo iwo Israeli kuro ninu ibinu gbigbona rẹ̀: o ti fà ọwọ ọtun rẹ̀ sẹhin niwaju ọta, o si jo gẹgẹ bi ọwọ iná ninu Jakobu ti o jẹrun yikakiri. 4 O ti fà ọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọta: o duro, o mura ọwọ ọtun rẹ̀ gẹgẹ bi aninilara, o si pa gbogbo ohun didara ti oju fẹ iri ni agọ ọmọbinrin Sioni, o dà irunu rẹ̀ jade bi iná. 5 Oluwa jẹ gẹgẹ bi ọta: o ti gbe Israeli mì, o ti gbe gbogbo ãfin rẹ̀ mì: o ti pa ilu olodi rẹ̀ run o si ti fi ibanujẹ lori ibanujẹ fun ọmọbinrin Juda. 6 O si ti wó ọgba rẹ̀ lulẹ, gẹgẹ bi àgbala: o ti pa ibi apejọ rẹ̀ run: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ-mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o ti fi ẹ̀gan kọ̀ ọba ati alufa silẹ ninu ikannu ibinu rẹ̀. 7 Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ tì, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi ogiri ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pa ariwo ninu ile Oluwa, gẹgẹ bi li ọjọ ajọ-mimọ́. 8 Oluwa ti rò lati pa odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn ìwọn jade, on kò ti ifa ọwọ rẹ̀ sẹhin kuro ninu ipanirun: bẹ̃ni o ṣe ki ile-iṣọ rẹ̀ ati odi rẹ̀ ki o ṣọ̀fọ; nwọn jumọ rẹ̀ silẹ. 9 Ẹnu-bode rẹ̀ wọnni rì si ilẹ; o ti parun o si ṣẹ́ ọpá idabu rẹ̀; ọba rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀ wà lãrin awọn orilẹ-ède: ofin kò si mọ; awọn woli rẹ̀ pẹlu kò ri iran lati ọdọ Oluwa. 10 Awọn àgbagba ọmọbinrin Sioni joko ni ilẹ, nwọn dakẹ: nwọn ti ku ekuru sori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu sọ ori wọn kọ́ si ilẹ. 11 Oju mi gbẹ tan fun omije, inu mi nho, a dà ẹ̀dọ mi sori ilẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi: nitoripe awọn ọmọ wẹ̃rẹ ati awọn ọmọ-ọmu nkulọ ni ita ilu na. 12 Nwọn nsọ fun iya wọn pe, Nibo ni ọka ati ọti-waini gbe wà? nigbati nwọn daku gẹgẹ bi awọn ti a ṣalọgbẹ ni ita ilu na, nigbati ọkàn wọn dà jade li aiya iya wọn. 13 Kili ohun ti emi o mu fi jẹri niwaju rẹ? kili ohun ti emi o fi ọ we, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu? kili emi o fi ba ọ dọgba, ki emi ba le tù ọ ninu, iwọ wundia ọmọbinrin Sioni? nitoripe ọgbẹ rẹ tobi gẹgẹ bi okun; tali o le wò ọ sàn? 14 Awọn woli rẹ ti riran ohun asan ati wère fun ọ: nwọn kò si ti fi aiṣedede rẹ hàn ọ, lati yi igbekun rẹ pada kuro; ṣugbọn nwọn ti riran ọ̀rọ-wiwo eke fun ọ ati imuniṣina. 15 Gbogbo awọn ti nkọja patẹwọ le ọ; nwọn nṣẹsin, nwọn si nmì ori wọn si ọmọbinrin Jerusalemu; pe, Ilu na ha li eyi, ti a npè ni: Pipe-ẹwà, Ayọ̀ gbogbo ilẹ aiye! 16 Gbogbo awọn ọta rẹ ya ẹnu wọn si ọ; nwọn nṣe ṣiọ! nwọn si npa ehin keke, nwọn wipe: Awa ti gbe e mì; dajudaju eyi li ọjọ na ti awa ti nwọ̀na fun; ọwọ ti tẹ̀ ẹ, awa ti ri i! 17 Oluwa ti ṣe eyi ti o ti rò; o ti mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti paṣẹ li ọjọ igbãni: o ti bì ṣubu, kò si dasi: o si ti mu ọta yọ̀ lori rẹ, o ti gbe iwo awọn aninilara rẹ soke. 18 Ọkàn wọn kigbe si Oluwa, iwọ odi ọmọbinrin Sioni, jẹ ki omije ṣan silẹ gẹgẹ bi odò lọsan ati loru; má fun ara rẹ ni isimi; máṣe jẹ ki ẹyin oju rẹ gbe jẹ. 19 Dide, kigbe soke li oru ni ibẹrẹ akoko iṣọ: tú ọkàn rẹ jade gẹgẹ bi omi niwaju Oluwa: gbe ọwọ rẹ soke si i fun ẹmi awọn ọmọ wẹwẹ rẹ, ti nkulọ fun ebi ni gbogbo ori-ita. 20 Wò o, Oluwa, ki o rò, fun tani iwọ ti ṣe eyi? Awọn obinrin ha le ma jẹ eso-inu wọn, awọn ọmọ-ọwọ ti nwọn npọ̀n? a ha le ma pa alufa ati woli ni ibi mimọ́ Oluwa? 21 Ewe ati arugbo dubulẹ ni ita wọnni: awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi ṣubu nipa idà: iwọ ti pa li ọjọ ibinu rẹ; iwọ ti pa, iwọ kò si dasi. 22 Iwọ ti kepe ẹ̀ru mi yikakiri gẹgẹ bi li ọjọ mimọ́, tobẹ̃ ti ẹnikan kò sala tabi kì o kù li ọjọ ibinu Oluwa: awọn ti mo ti pọ̀n ti mo si tọ́, ni ọta mi ti run. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria