Ẹk. Jer 1 - Bibeli MimọÌbànújẹ́ Jerusalẹmu 1 BAWO ni ilu ṣe joko nikan, eyi ti o ti kún fun enia! o wà bi opó! on ti iṣe ẹni-nla lãrin awọn orilẹ-ède! ọmọ-alade obinrin lãrin igberiko, on di ẹrú! 2 On sọkun gidigidi li oru, omije rẹ̀ si wà ni ẹ̀rẹkẹ rẹ̀: lãrin gbogbo awọn olufẹ rẹ̀, kò ni ẹnikẹni lati tù u ninu: gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ ti ba a lo ẹ̀tan, nwọn di ọta rẹ̀. 3 Juda lọ si àjo nitori ipọnju ati isin-ẹrú nla: o joko lãrin awọn orilẹ-ède, on kò ri isimi: gbogbo awọn ti nlepa rẹ̀ ba a ni ibi hiha. 4 Ọ̀na Sioni wọnni nṣọ̀fọ, nitori ẹnikan kò wá si ajọ-mimọ́: gbogbo ẹnu-bode rẹ̀ dahoro: awọn alufa rẹ̀ kẹdun, awọn wundia rẹ̀ nkãnu, on si wà ni kikoro ọkàn. 5 Awọn aninilara rẹ̀ bori, awọn ọta rẹ̀ ri rere: nitori Oluwa ti pọn ọ loju nitori ọ̀pọlọpọ irekọja rẹ̀; awọn ọmọ wẹrẹ rẹ̀ lọ si igbekun niwaju awọn aninilara. 6 Gbogbo ẹwà ọmọbinrin Sioni si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀: awọn ijoye rẹ̀ dabi agbọnrin ti kò ri pápá oko tutu, nwọn si lọ laini agbara niwaju alepa nì, 7 Li ọjọ ipọnju rẹ̀ ati inilara rẹ̀ ni Jerusalemu ranti gbogbo ohun daradara ti o ti ni li ọjọ igbãni, nigbati awọn enia rẹ̀ ṣubu si ọwọ ọta, ẹnikan kò si ràn a lọwọ: awọn aninilara ri i, nwọn si fi iparun rẹ̀ ṣẹsin. 8 Jerusalemu ti da ẹ̀ṣẹ gidigidi, nitorina li o ṣe di ẹni-irira: gbogbo awọn ti mbu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoripe nwọn ri ihoho rẹ̀: lõtọ on kẹdùn, o si yi ẹ̀hin pada. 9 Ẽri rẹ̀ wà ni iṣẹti aṣọ rẹ̀; on kò si ranti opin rẹ̀ ikẹhin; nitorina ni o ṣe sọkalẹ ni isọkalẹ iyanu: kò ni olutunu, Oluwa, wò ipọnju mi, nitori ọta ti bori! 10 Aninilara ti nà ọwọ rẹ̀ jade sori gbogbo ohun daradara rẹ̀: nitori on ti ri pe awọn orilẹ-ède wọ ibi-mimọ́ rẹ̀, eyiti iwọ paṣẹ pe, nwọn kì o wọ inu ijọ tirẹ. 11 Gbogbo awọn enia rẹ̀ kẹdùn, nwọn wá onjẹ; nwọn fi ohun daradara fun onjẹ lati tu ara wọn ninu. Wò o, Oluwa, ki o si rò! nitori emi di ẹni-ẹ̀gan. 12 Kò ha kàn nyin bi, gbogbo ẹnyin ti nkọja? Wò o, ki ẹ si ri bi ibanujẹ kan ba wà bi ibanujẹ mi, ti a ṣe si mi! eyiti Oluwa fi pọn mi loju li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀. 13 Lati oke li a ti rán iná sinu egungun mi, o si ràn ninu rẹ̀: On ti nà àwọn fun ẹsẹ mi, o ti yi mi pada sẹhin; O ti mu mi dahoro, mo si rẹ̀wẹsi lojojumọ. 14 Okùn àjaga irekọja mi li a dimu li ọwọ rẹ̀; a so wọn pọ̀: nwọn yi ọrùn mi ka, nwọn tẹ agbara mi mọlẹ; Oluwa ti fi mi le ọwọ awọn ẹniti emi kò le dide si. 15 Oluwa ti tẹ̀ gbogbo awọn akọni mi mọlẹ labẹ ẹsẹ li arin mi: On ti pe apejọ sori mi lati tẹ̀ awọn ọdọmọkunrin mi rẹ́: Oluwa ti tẹ ifunti fun wundia, ọmọbinrin Juda. 16 Emi nsọkun nitori nkan wọnyi; oju mi! oju mi ṣàn omi silẹ, nitoripe olutunu ati ẹniti iba mu ọkàn mi sọji jina si mi: awọn ọmọ mi run, nitoripe ọta bori. 17 Sioni nà ọwọ rẹ̀ jade, kò si sí ẹnikan lati tù u ninu: Oluwa ti paṣẹ niti Jakobu pe, ki awọn aninilara rẹ̀ ki o yi i kakiri: Jerusalemu dabi obinrin ẹlẹgbin lãrin wọn. 18 Oluwa ṣe olododo; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ si aṣẹ ẹnu rẹ̀: gbọ́, (emi bẹ nyin,) gbogbo orilẹ-ède, ẹ si wò ikãnu mi; awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi lọ si igbekun. 19 Emi pè awọn olufẹ mi, awọn wọnyi tàn mi jẹ: awọn alufa mi, ati àgbagba mi jọwọ ẹmi wọn lọwọ ni ilu, nigbati nwọn nwá onjẹ wọn lati mu ẹmi wọn sọji. 20 Wò o, Oluwa: nitoriti emi wà ninu ipọnju: inu mi nhó; ọkàn mi yipada ninu mi; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ gidigidi: lode, idà sọni di alailọmọ, ni ile, o dabi ikú! 21 Nwọn gbọ́ bi emi ti nkẹdùn to: sibẹ kò si olutunu fun mi: gbogbo awọn ọta mi gbọ́ iyọnu mi; inu wọn dùn nitori iwọ ti ṣe e: iwọ o mu ọjọ na wá ti iwọ ti dá, nwọn o si ri gẹgẹ bi emi. 22 Jẹ ki gbogbo ìwa-buburu wọn wá si iwaju rẹ; si ṣe si wọn, gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si mi nitori gbogbo irekọja mi: nitori ikẹdùn mi pọ̀, ọkàn mi si rẹ̀wẹsi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria