Daniẹli 10 - Bibeli MimọÌran tí Daniẹli Rí ní Odò Hiddekeli 1 LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na. 2 Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako. 3 Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹ̃ni kò si si ẹran tabi ọti-waini ti o wá si ẹnu mi, bẹ̃li emi kò fi ororo kùn ara mi rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe. 4 Nigbati o di ọjọ kẹrinlelogun oṣu kini, bi mo ti wà li eti odò nla, ti ijẹ Hiddekeli; 5 Nigbana ni mo gbé oju mi soke, mo wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti o wọ̀ aṣọ àla, ẹ̀gbẹ ẹniti a fi wura Ufasi daradara dì li àmure: 6 Ara rẹ̀ pẹlu dabi okuta berili, oju rẹ̀ si dabi manamána, ẹyinju rẹ̀ dabi iná fitila, apa ati ẹsẹ rẹ̀ li awọ̀ ti o dabi idẹ ti a wẹ̀ dan, ohùn ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ si dabi ohùn ijọ enia pupọ. 7 Emi Danieli nikanṣoṣo li o si ri iran na, awọn ọkunrin ti o si wà pẹlu mi kò ri iran na; ṣugbọn ìwariri nlanla dà bò wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi sá lọ lati fi ara wọn pamọ́. 8 Nitorina emi nikan li o kù, ti mo si ri iran nla yi, kò si kù agbara ninu mi: ẹwà mi si yipada lara mi di ibajẹ, emi kò si lagbara mọ. 9 Sibẹ mo gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀: nigbati mo si gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀, nigbana ni mo dãmu, mo si wà ni idojubolẹ̀. 10 Sa si kiyesi i, ọwọ kan kàn mi, ti o gbé mi dide lori ẽkun mi, ati lori atẹlẹwọ mi. 11 O si wi fun mi pe, Danieli, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, ki oye ọ̀rọ ti mo nsọ fun ọ ki o ye ọ, ki o si duro ni ipò rẹ: nitoripe iwọ li a rán mi si nisisiyi. Nigbati on ti sọ̀rọ bayi fun mi, mo dide duro ni ìwariri. 12 Nigbana ni o wi fun mi pe, má bẹ̀ru, Danieli: lati ọjọ kini ti iwọ ti fi aiya rẹ si lati moye, ti iwọ si npọ́n ara rẹ loju niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ rẹ, emi si wá nitori ọ̀rọ rẹ. 13 Ṣugbọn balogun ijọba Persia nì dè mi li ọ̀na li ọjọ mọkanlelogun: ṣugbọn, wò o, Mikaeli, ọkan ninu awọn olori balogun wá lati ràn mi lọwọ: emi si di ipò mi mu lọdọ awọn ọba Persia. 14 Njẹ nisisiyi, mo de lati mu ọ moye ohun ti yio ba awọn enia rẹ ni ikẹhin ọjọ: nitori ti ọjọ pipọ ni iran na iṣe. 15 Nigbati o si ti sọ iru ọ̀rọ bayi fun mi tan, mo dojukọ ilẹ mo si yadi. 16 Si wò o, ẹnikan ti jijọ rẹ̀ dabi ti awọn ọmọ enia fi ọwọ kan ète mi: nigbana ni mo ya ẹnu mi, mo si fọhùn, mo si wi fun ẹniti o duro tì mi pe, oluwa mi, niti iran na, irora mi pada sinu mi, emi kò si lagbara mọ. 17 Nitoripé bawo ni ọmọ-ọdọ oluwa mi yi yio ti ṣe le ba oluwa mi yi sọ̀rọ? ṣugbọn bi o ṣe temi ni, lojukanna, agbara kò kù ninu mi, bẹ̃ni kò si kù ẽmi ninu mi. 18 Nigbana ni ẹnikan ti o ni aworan enia wá o si tun fi ọwọ tọ́ mi, o si mu mi lara le, 19 O si wipe, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, má bẹ̀ru: alafia ni fun ọ, mu ara le. Ani mu ara le, Nigbati on ba mi sọ̀rọ, a si mu mi lara le, mo si wipe, Ki oluwa mi ki o ma sọ̀rọ, nitoriti iwọ ti mu mi lara le. 20 Nigbana ni o wipe, Iwọ, ha mọ̀ idi ohun ti mo tọ̀ ọ wá si? nisisiyi li emi o si yipada lọ iba balogun Persia jà: nigbati emi ba si jade lọ, kiyesi i, balogun Hellene yio wá. 21 Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria