Amosi 7 - Bibeli MimọÌran Nípa Eeṣú 1 BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi; si wò o, o dá ẽṣú ni ibẹ̀rẹ irú-soke idàgba ikẹhin, si wò o, idàgba ikẹhìn lẹhìn ike-kuro ti ọba nì. 2 O si ṣe, ti nwọn jẹ koriko ilẹ na tan, nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, darijì, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. 3 Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Kì yio ṣe, li Oluwa wi. Ìran Nípa Iná 4 Bayi li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si wò o, Oluwa Ọlọrun pè lati fi iná jà, o si jó ibú nla nì run, o si jẹ apakan run. 5 Nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, dawọ duro, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. 6 Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Eyi pẹlu kì yio ṣe, li Oluwa Ọlọrun wi. Ìran Nípa Okùn Ìwọ̀n Àwọn Mọlémọlé 7 Bayi li on fi hàn mi: si wò o, Oluwa duro lori odi kan, ti a fi okùn-ìwọn ti o run mọ, ti on ti okùn-ìwọn ti o run li ọwọ́ rẹ̀. 8 Oluwa si wi fun mi pe, Amosi, kini iwọ ri? Emi si wipe, Okùn-ìwọn kan ti o run ni. Nigbana ni Oluwa wipe, Wò o, emi o fi okùn-ìwọn rirun kan le ilẹ lãrin Israeli enia mi: emi kì yio si tun kọja lọdọ wọn mọ: 9 Ibi giga Israeli wọnni yio si di ahoro: ati ibi mimọ́ Israeli wọnni yio di ahoro; emi o si fi idà dide si ile Jeroboamu. Amosi ati Amasiah 10 Nigbana ni Amasiah, alufa Beteli ranṣẹ si Jeroboamu ọba Israeli, wipe, Amosi ti ditẹ̀ si ọ lãrin ile Israeli: ilẹ kò si le gba gbogbo ọ̀rọ rẹ̀. 11 Nitori bayi li Amosi wi, Jeroboamu yio ti ipa idà kú, nitõtọ Israeli li a o si fà lọ si igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀. 12 Amasiah sọ fun Amosi pẹlu pe, Iwọ ariran, lọ, salọ si ilẹ Juda, si ma jẹun nibẹ̀, si ma sọtẹlẹ nibẹ̀: 13 Ṣugbọn máṣe sọtẹlẹ̀ mọ ni Beteli: nitori ibi mimọ́ ọba ni, ãfin ọba si ni. 14 Nigbana ni Amosi dahùn, o si wi fun Amasiah pe, Emi ki iṣe woli ri, bẹ̃ni emi kì iṣe ọmọ woli, ṣugbọn olùṣọ-agùtan li emi ti iṣe ri, ati ẹniti iti ma ká eso ọpọ̀tọ: 15 Oluwa si mu mi, bi mo ti ntọ̀ agbo-ẹran lẹhìn, Oluwa si wi fun mi pe, Lọ, sọtẹlẹ̀ fun Israeli enia mi. 16 Njẹ nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Iwọ wipe, Máṣe sọtẹlẹ̀ si Israeli, má si jẹ ki ọ̀rọ rẹ kán silẹ si ile Isaaki. 17 Nitorina bayi li Oluwa wi; Obinrin rẹ yio di panṣagà ni ilu, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, yio ti ipa idà ṣubu; ilẹ rẹ li a o si fi okùn pin; iwọ o si kú ni ilẹ aimọ́: nitõtọ, a o si kó Israeli lọ ni igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria