Amosi 3 - Bibeli Mimọ1 Ẹ gbọ̀ ọ̀rọ yi ti Oluwa ti sọ si nyin, ẹnyin ọmọ Israeli, si gbogbo idile ti mo mú goke lati ilẹ Egipti wá, wipe, 2 Ẹnyin nikan ni mo mọ̀ ninu gbogbo idile aiye: nitorina emi o bẹ̀ nyin wò nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin. Iṣẹ́ Wolii 3 Ẹni meji lè rìn pọ̀, bikòṣepe nwọn rẹ́? 4 Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ọmọ kiniun yio ha ké jade ninu ihò rẹ̀, bi kò ri nkan mu? 5 Ẹiyẹ le lu okùn ni ilẹ, nibiti okùn didẹ kò gbe si fun u? okùn ha le ré kuro lori ilẹ, laijẹ pe o mu nkan rara? 6 A le fun ipè ni ilu, ki awọn enia má bẹ̀ru? tulasi ha le wà ni ilu, ki o má ṣepe Oluwa li o ṣe e? 7 Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀. 8 Kiniun ti ké ramùramù, tani kì yio bẹ̀ru? Oluwa Ọlọrun ti sọ̀rọ, tani lè ṣe aisọtẹlẹ? Ìparun Samaria 9 Ẹ kede li ãfin Aṣdodu, ati li ãfin ni ilẹ Egipti, ki ẹ si wipe, Pè ara nyin jọ lori awọn oke nla Samaria, ki ẹ si wò irọkẹ̀kẹ nla lãrin rẹ̀, ati inilara lãrin rẹ̀. 10 Nitori nwọn kò mọ̀ bi ati ṣe otitọ, li Oluwa wi, nwọn ti kó ìwa-ipá ati ìwa-olè jọ li ãfin wọn. 11 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ọta kan yio si wà yi ilẹ na ka; on o si sọ agbara rẹ kalẹ kuro lara rẹ, a o si kó ãfin rẹ wọnni. 12 Bayi li Oluwa wi; gẹgẹ bi oluṣọ-agùtan iti gbà itan meji kuro li ẹnu kiniun, tabi ẹlà eti kan; bẹ̃li a o mu awọn ọmọ Israeli ti ngbe Samaria kuro ni igun akete, ati ni aṣọ Damasku irọ̀gbọku. 13 Ẹ gbọ́, ẹ si jẹri si ile Jakobu, li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, 14 Pe, li ọjọ ti emi o bẹ̀ irekọja Israeli wò lara rẹ̀, emi o bẹ̀ awọn pẹpẹ Beteli wò pẹlu: a o si ké iwo pẹpẹ kuro, nwọn o si wó lulẹ. 15 Emi o si lù ile otutù pẹlu ile ẹ̃rùn; ile ehín erin yio si ṣègbe, ile nla wọnni yio si li opin, li Oluwa wi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria