3 Johanu 1 - Bibeli MimọÌkíni 1 ALÀGBA si Gaiu olufẹ, ẹniti mo fẹ ninu otitọ. 2 Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ. 3 Nitori mo yọ̀ gidigidi, nigbati awọn arakunrin de ti nwọn si jẹri si otitọ rẹ, ani bi iwọ ti nrìn ninu otitọ. 4 Emi kò ni ayọ̀ ti o pọjù eyi lọ, ki emi ki o mã gbọ́ pe, awọn ọmọ mi nrìn ninu otitọ. Àjọṣepọ̀ 5 Olufẹ, iwọ nṣe iṣẹ igbagbọ li ohunkohun ti o bá nṣe fun awọn ti iṣe ará ati fun awọn alejò; 6 Ti nwọn jẹri ifẹ rẹ niwaju ijọ: bi ìwọ bá npese fun wọn li ọna ajo wọn bi o ti yẹ nipa ti Ọlọrun, iwọ o ṣe ohun ti o dara. 7 Nitoripe nitori orukọ rẹ̀ ni nwọn ṣe jade lọ, li aigbà ohunkohun lọwọ awọn Keferi. 8 Njẹ o yẹ ki awa ki o gbà irú awọn wọnni, ki awa ki o le jẹ́ alabaṣiṣẹpọ pẹlu otitọ. Diotirefe lòdì sí wa 9 Emi kọwe si ijọ: ṣugbọn Diotrefe, ẹniti o fẹ lati jẹ olori larin wọn, kò gbà wa. 10 Nitorina bi mo ba de, emi o mu iṣẹ rẹ̀ ti o ṣe wá si iranti, ti o nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa: eyini kò si tẹ́ ẹ lọrùn, bẹ̃ni on tikararẹ̀ kò gbà awọn ará, awọn ti o si nfẹ gbà wọn, o ndá wọn lẹkun, o si nlé wọn jade kuro ninu ijọ. Ọ̀rọ̀ Ìyànjú 11 Olufẹ, máṣe afarawe ohun ti iṣe ibi, bikoṣe ohun ti iṣe rere. Ẹniti o ba nṣe rere ti Ọlọrun ni: ẹniti o ba nṣe buburu kò ri Ọlọrun. 12 Demetriu li ẹri rere lọdọ gbogbo enia ati ti otitọ tikararẹ̀ pẹlu: nitõtọ, awa pẹlu si gbà ẹrí rẹ̀ jẹ; ẹnyin si mọ̀ pe otitọ ni ẹrí wa. Ó Dìgbà Díẹ̀ 13 Emi ní ohun pupọ̀ lati kọwe si ọ, ṣugbọn emi kò fẹ fi tàdãwa on kalamu kọ wọn. 14 Ṣugbọn mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, a o si sọrọ li ojukoju. 15 Alafia fun ọ. Awọn ọrẹ́ kí ọ. Kí awọn ọrẹ́ li ọkọ̃kan. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria