Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

2 Samuẹli 22 - Bibeli Mimọ


Orin ìṣẹ́gun tí Dafidi kọ
( O. Daf 18 )

1 DAFIDI si sọ ọ̀rọ orin yi si Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro li ọwọ́ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati kuro li ọwọ́ Saulu.

2 O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi;

3 Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara.

4 Emi o kepe Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn: a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.

5 Nigbati ibilu irora ikú yi mi ka kiri, ti awọn iṣàn enia buburu dẹruba mi;

6 Ọjá ipo-okú yi mi ka kiri; ikẹkun ikú ti ṣaju mi.

7 Ninu ipọnju mi emi ke pe Oluwa, emi si gbe ohùn mi soke si Ọlọrun mi: o si gbohùn mi lati tempili rẹ̀ wá, igbe mi si wọ̀ eti rẹ̀.

8 Ilẹ si mì, o si wariri; ipilẹ ọrun wariri, o si mì, nitoriti o binu.

9 Ẽfin si jade lati iho-imu rẹ̀ wa, ina lati ẹnu rẹ̀ wa si njonirun, ẹyín si nràn nipasẹ rẹ̀.

10 O tẹ ori ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ; okunkun biri-biri si mbẹ li atẹlẹsẹ rẹ̀.

11 O si gun ori kerubu, o si fò: a si ri i lori iyẹ afẹfẹ.

12 O si fi okunkun ṣe ibujoko yi ara rẹ̀ ka, ati agbajọ omi, ani iṣududu awọ sanma.

13 Nipasẹ imọlẹ iwaju rẹ̀ ẹyin-iná ràn.

14 Oluwa san ãra lati ọrun wá, ọga-ogo julọ si fọhùn rẹ̀.

15 O si ta ọfà, o si tú wọn ka; o kọ màna-mána, o si ṣẹ wọn.

16 Iṣàn ibu okun si fi ara hàn, ipilẹ aiye fi ara hàn, nipa ibawi Oluwa, nipa fifún ẽmi ihò imu rẹ̀.

17 O ranṣẹ lati oke wá, o mu mi; o fà mi jade lati inu omi nla wá.

18 O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, lọwọ awọn ti o korira mi: nitoripe nwọn li agbara jù mi lọ.

19 Nwọn ṣaju mi li ọjọ ipọnju mi; ṣugbọn Oluwa li alafẹhinti mi.

20 O si mu mi wá si àye nla: o gbà mi, nitoriti inu rẹ̀ dùn si mi.

21 Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi: o si san a fun mi gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ́ mi.

22 Nitoripe emi pa ọ̀na Oluwa mọ, emi kò si fi ìwa buburu yapa kuro lọdọ Ọlọrun mi.

23 Nitoripe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi: ati niti ofin rẹ̀, emi kò si yapa kuro ninu wọn.

24 Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.

25 Oluwa si san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi ìwa-mimọ́ mi niwaju rẹ̀.

26 Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu, ati fun ẹni-iduro-ṣinṣin li ododo ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin li ododo.

27 Fun oninu-funfun ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni funfun: ati fun ẹni-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni wiwọ.

28 Awọn enia ti o wà ninu iyà ni iwọ o si gbàla: ṣugbọn oju rẹ wà lara awọn agberaga, lati rẹ̀ wọn silẹ.

29 Nitori iwọ ni imọlẹ mi, Oluwa: Oluwa yio si sọ okunkun mi di imọlẹ.

30 Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan.

31 Pipe li Ọlọrun li ọ̀na rẹ̀; ọ̀rọ Oluwa li a ti dan wò: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.

32 Nitori tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta, bikoṣe Ọlọrun wa?

33 Ọlọrun alagbara li o fun mi li agbara, o si sọ ọ̀na mi di titọ́.

34 O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ agbọnrin: o si mu mi duro ni ibi giga mi.

35 O kọ ọwọ́ mi ni ogun jijà; tobẹ̃ ti apá mi fà ọrun idẹ.

36 Iwọ si ti fun mi li asà igbala rẹ: irẹlẹ rẹ si ti sọ mi di nla.

37 Iwọ si sọ itẹlẹ mi di nla li abẹ mi; tobẹ̃ ti ẹsẹ mi kò fi yọ̀.

38 Emi ti lepa awọn ọta mi, emi si ti run wọn; emi kò pẹhinda titi emi fi run wọn.

39 Emi ti pa wọn run, emi si ti fọ́ wọn, nwọn kò si le dide mọ: nwọn ṣubu labẹ ẹsẹ mi.

40 Iwọ si ti fi agbara di mi li amure fun ijà: awọn ti o ti dide si mi ni iwọ si ti tẹ̀ li ori ba fun mi.

41 Iwọ si mu awọn ọta mi pẹhindà fun mi, emi si pa awọn ti o korira mi run.

42 Nwọn wò, ṣugbọn kò si ẹnikan lati gbà wọn; nwọn wò Oluwa, ṣugbọn kò da wọn lohùn.

43 Nigbana ni emi si gun wọn wẹwẹ bi erupẹ ilẹ, emi si tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita, emi si tẹ wọn gbọrọ.

44 Iwọ si gbà mi kuro lọwọ ijà awọn enia mi, iwọ pa mi mọ ki emi ki o le ṣe olori awọn ajeji orilẹ-ède: awọn enia ti emi kò ti mọ̀ yio ma sìn mi.

45 Awọn alejo yio fi ẹ̀tan tẹriba fun mi: bi nwọn ba ti gbọ́ iró mi, nwọn o si gbọ́ ti emi.

46 Ìpaiyà yio dé bá awọn alejo, nwọn o si ma bẹ̀ru nibi kọ́lọfin wọn.

47 Oluwa mbẹ; olubukun si ni apata mi: gbigbega si li Ọlọrun apata igbala mi.

48 Ọlọrun li ẹniti ngbẹsan mi, ati ẹniti nrẹ̀ awọn enia silẹ labẹ mi.

49 On ni o gbà mi kuro lọwọ awọn ọta mi: iwọ si gbe mi soke ju awọn ti o dide si mi lọ: iwọ si gbà mi kuro lọwọ ọkunrin ìwa agbara.

50 Nitorina emi o fi ọpẹ fun ọ. Oluwa, larin awọn ajeji orilẹ-ède: emi o si kọrin si orukọ rẹ.

51 On ni ile-iṣọ igbala fun ọba rẹ̀: o si fi ãnu hàn fun ẹni-ami-ororo rẹ̀; fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ titi lailai.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan