2 Samuẹli 21 - Bibeli MimọWọ́n pa àwọn Ọmọ Ọmọ Saulu 1 IYAN kan si mu ni ọjọ Dafidi li ọdun mẹta, lati ọdun de ọdun; Dafidi si bere lọdọ Oluwa, Oluwa si wipe, Nitori ti Saulu ni, ati nitori ile rẹ̀ ti o kún fun ẹ̀jẹ̀, nitoripe o pa awọn ara Gibeoni. 2 Ọba si pe awọn ara Gibeoni, o si ba wọn sọ̀rọ: awọn ara Gibeoni ki iṣe ọkan ninu awọn ọmọ Israeli, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Amori; awọn ọmọ Israeli si ti bura fun wọn: Saulu si nwá ọ̀na ati pa wọn ni itara rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli ati Juda. 3 Dafidi si bi awọn ara Gibeoni lere pe, Kili emi o ṣe fun nyin? ati kili emi o fi ṣe etutu, ki ẹnyin ki o le sure fun ilẹ ini Oluwa? 4 Awọn ara Gibeoni si wi fun u pe, Awa kò ni fi fadaka tabi wura ti Saulu ati ti idile rẹ̀ ṣe, bẹ̃ni a kò si fẹ ki ẹ pa ẹnikan ni Israeli. O si wipe, eyi ti ẹnyin ba wi li emi o ṣe. 5 Nwọn si wi fun ọba pe, ọkunrin ti o run wa, ti o si rò lati pa wa rẹ́ ki a má kù nibikibi ninu gbogbo agbegbe Israeli. 6 Mu ọkunrin meje ninu awọn ọmọ rẹ̀ fun wa, awa o si so wọn rọ̀ fun Oluwa ni Gibea ti Saulu ẹniti Oluwa ti yàn. Ọba si wipe, Emi o fi wọn fun nyin. 7 Ṣugbọn Ọba dá Mefiboṣeti si, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nitori ibura Oluwa ti o wà larin wọn, lãrin Dafidi ati Jonatani ọmọ Saulu. 8 Ọba si mu awọn ọmọkunrin mejeji ti Rispa ọmọbinrin Aia bi fun Saulu, ani Armoni ati Mefiboṣeti: ati awọn ọmọkunrin mararun ti Merabu, ọmọbinrin Saulu, awọn ti o bi fun Adrieli ọmọ Barsillai ara Meholati. 9 On si fi wọn le awọn ara Gibea lọwọ, nwọn si so wọn rọ̀ lori oke niwaju Oluwa: awọn mejeje si ṣubu lẹ̃kan, a si pa wọn ni igbà ikore, ni ibẹrẹ ikore ọka-barle. 10 Rispa ọmọbinrin Aia si mu aṣọ ọfọ̀ kan, o si tẹ́ ẹ fun ara rẹ̀ lori àpata, ni ibẹrẹ ikore, titi omi fi dà si wọn lara lati ọrun wá, kò si jẹ ki awọn ẹiyẹ oju ọrun bà le wọn li ọsan, tabi awọn ẹranko igbẹ li oru. 11 A si rò eyi, ti Rispa ọmọbinrin Aia obinrin Saulu ṣe, fun Dafidi. 12 Dafidi si lọ o si ko egungun Saulu, ati egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọkunrin Jabeṣi-gileadi, awọn ti o ti ji wọn kuro ni ita Betṣani, nibiti awọn Filistini gbe so wọn rọ̀, nigbati awọn Filistini pa Saulu ni Gilboa. 13 On si mu egungun Saulu ati egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ lati ibẹ na wá; nwọn si ko egungun awọn ti a ti so rọ̀ jọ. 14 Nwọn si sin egungun Saulu ati ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ni ilẹ Benjamini, ni Sela, ninu iboji Kiṣi baba rẹ̀: nwọn si ṣe gbogbo eyi ti ọba pa li aṣẹ: lẹhin eyini Ọlọrun si gbà ẹbẹ nitori ilẹ na. Wọ́n Bá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun ( I. Kro 20:4-8 ) 15 Ogun si tun wà larin awọn Filistini ati Israeli; Dafidi si sọkalẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si ba awọn Filistini jà: o si rẹ̀ Dafidi. 16 Iṣbi-benobu si jẹ ọkan ninu awọn òmirán, ẹniti òṣuwọn ọ̀kọ rẹ̀ jẹ ọdunrun ṣekeli idẹ, on si sán idà titun, o si gbero lati pa Dafidi. 17 Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia si ràn a lọwọ, o si kọlu Filistini na, o si pa a. Nigbana ni awọn iranṣẹ Dafidi si bura fun u, pe, Iwọ kì yio si tun ba wa jade lọ si ibi ija mọ, ki iwọ ki o máṣe pa iná Israeli. 18 O si ṣe, lẹhin eyi, ija kan si tun wà lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini ni Gobu: nigbana ni Sibbekai ara Huṣa pa Safu, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn òmirán. 19 Ija kan si tun wà ni Gobu lãrin awọn Israeli ati awọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ara Betlehemu si pa arakunrin Goliati ara Gati, ẹniti ọpá ọ̀kọ rẹ̀ dabi idabú igi ti a fi hun aṣọ. 20 Ija kan si tun wà ni Gati, ọkunrin kan si wà ti o gùn pupọ, o si ni ika mẹfa li ọwọ́ kan, ati ọmọ-ẹsẹ mẹfa li ẹsẹ kan, apapọ̀ rẹ̀ si jẹ mẹrinlelogun; a si bi on na li òmirán. 21 Nigbati on si pe Israeli ni ijà, Jonatani ọmọ Ṣimei arakunrin Dafidi si pa a. 22 Awọn mẹrẹrin wọnyi li a bi li òmirán ni Gati, nwọn si ti ọwọ́ Dafidi ṣubu, ati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria