Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

2 Samuẹli 20 - Bibeli Mimọ


Ọ̀tẹ̀ Ṣeba

1 Ọkunrin Beliali kan si mbẹ nibẹ orukọ rẹ̀ si njẹ Ṣeba ọmọ Bikri ara Benjamini; o si fún ipè o si wipe, Awa kò ni ipa ni Dafidi, bẹ̃li awa kò ni ini ni ọmọ Jesse: ki olukuluku ọkunrin lọ si agọ rẹ̀, ẹnyin Israeli.

2 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si lọ kuro lẹhin Dafidi, nwọn si ntọ Ṣeba ọmọ Bikri lẹhin: ṣugbọn awọn ọkunrin Juda si fi ara mọ́ ọba wọn lati odo Jordani wá titi o fi de Jerusalemu.

3 Dafidi si wá si ile rẹ̀ ni Jerusalemu; ọba si mu awọn obinrin mẹwa ti iṣe alè rẹ̀, awọn ti o ti fi silẹ lati ma ṣọ́ ile. O si há wọn mọ ile, o si mbọ́ wọn, ṣugbọn kò si tun wọle tọ̀ wọn mọ a si se wọn mọ titi di ọjọ ikú wọn, nwọn si wà bi opo.

4 Ọba si wi fun Amasa pe, Pe awọn ọkunrin Juda fun mi niwọn ijọ mẹta oni, ki iwọ na ki o si wá nihinyi.

5 Amasa si lọ lati pe awọn ọkunrin Juda: ṣugbọn o si duro pẹ jù akoko ti o fi fun u.

6 Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Nisisiyi Ṣeba ọmọ Bikri yio ṣe wa ni ibi jù ti Absalomu lọ; iwọ mu awọn iranṣẹ Oluwa rẹ, ki o si lepa rẹ̀, ki o ma ba ri ilu olodi wọ̀, ki o si bọ́ lọwọ wa,

7 Awọn ọmọkunrin Joabu si jade tọ̀ ọ lọ, ati awọn Kereti, ati awọn Peleti, ati gbogbo awọn ọkunrin alagbara: nwọn si ti Jerusalemu jade lọ, lati lepa Ṣeba ọmọ Bikri.

8 Nigbati nwọn de ibi okuta nla ti o wà ni Gibeoni, Amasa si ṣaju wọn. Joabu si di amùre si agbada rẹ̀ ti o wọ̀, o si sán idà rẹ̀ mọ idi, ninu akọ̀ rẹ̀, bi o si ti nlọ, o yọ jade.

9 Joabu si bi Amasa lere pe, Ara rẹ ko le bi, iwọ arakunrin mi? Joabu si na ọwọ́ ọtún rẹ̀ di Amasa ni irungbọ̀n mu lati fi ẹnu kò o li ẹnu.

10 Ṣugbọn Amasa ko si kiyesi idà ti mbẹ li ọwọ́ Joabu: bẹ̃li on si fi gun u li ẽgun ìha ikarun, ifun rẹ̀ si tú dá silẹ, on kò si tun gún u mọ́; o si kú. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si lepa Ṣeba ọmọ Bikri.

11 Ọkan ninu awọn ọdọmọdekunrin ti o wà lọdọ Joabu si duro tì i, o si wipe, Tali ẹni ti o ba fẹran Joabu? tali o si nṣe ti Dafidi, ki o ma tọ̀ Joabu lẹhin.

12 Amasa si nyira ninu ẹ̀jẹ larin ọ̀na. Ọkunrin na si ri pe gbogbo enia si duro tì i, o si gbe Amasa kuro loju ọ̀na lọ sinu ìgbẹ́, o si fi aṣọ bò o, nigbati o ti ri pe ẹnikẹni ti o ba de ọdọ rẹ̀, a duro.

13 Nigbati o si gbe e kuro li oju ọ̀na, gbogbo enia si tọ̀ Joabu lẹhin lati lepa Ṣeba ọmọ Bikri.

14 On kọja ninu gbogbo ẹya Israeli si Abeli ati si Betmaaka, ati gbogbo awọn ara Beriti; nwọn si kó ara wọn jọ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin pẹlu.

15 Nwọn wá, nwọn si do tì i ni Abeli ti Betmaaka, nwọn si mọdi tì ilu na, odi na si duro ti odi ilu na: gbogbo enia ti mbẹ lọdọ Joabu si ngbiyanju lati wó ogiri na lulẹ.

16 Obinrin ọlọgbọ́n kan si kigbe soke lati ilu na wá, pe, Fetisilẹ, fetisilẹ, emi bẹ̀ nyin, sọ fun Joabu pe, Sunmọ ihinyi emi o si ba ọ sọ̀rọ.

17 Nigbati on si sunmọ ọdọ rẹ̀, obinrin na si wipe, Iwọ ni Joabu bi? on si dahùn wipe, Emi na ni. Obinrin na si wi fun u pe, Gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ. On si dahun wipe, Emi ngbọ́.

18 O si sọ̀rọ, wipe, Nwọn ti nwi ṣaju pe niti bibere, nwọn o bere ni Abeli: bẹ̃ni nwọn si pari ọ̀ran na.

19 Emi li ọkan ninu awọn ẹni alafia ati olõtọ ni Israeli: iwọ nwá ọ̀na lati pa ilu kan run ti o jẹ iyá ni Israeli: ẽṣe ti iwọ o fi gbe ini Oluwa mì?

20 Joabu si dahùn wipe, Ki a má ri i, ki a má ri i lọdọ mi pe emi gbé mì tabi emi sì parun.

21 Ọràn na kò ri bẹ̃; ṣugbọn ọkunrin kan lati oke Efraimu, ti orukọ rẹ̀ njẹ Ṣeba, ọmọ Bikri, li o gbe ọwọ́ rẹ̀ soke si ọba, ani si Dafidi: fi on nikanṣoṣo le wa lọwọ, emi o si fi ilu silẹ. Obinrin na si wi fun Joabu pe, Wõ, ori rẹ̀ li a o si sọ si ọ lati inu odi wá.

22 Obinrin na si mu ìmọran rẹ̀ tọ gbogbo awọn enia na. Nwọn si bẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri li ori, nwọn si sọ ọ si Joabu. On si fún ipè, nwọn si tuka kuro ni ilu na, olukuluku si agọ rẹ̀. Joabu si pada lọ si Jerusalemu ati sọdọ ọba.


Àwọn adarí àwọn Òṣìṣẹ́ ní ààfin Dafidi

23 Joabu si li olori gbogbo ogun Israeli: Benaiah ọmọ Jehoiada si jẹ olori awọn Kereti, ati olori awọn Peleti:

24 Adoramu si jẹ olori awọn agbowodè: Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si jẹ akọwe nkan ti o ṣe ni ilu:

25 Ṣefa si jẹ akọwe: Sadoku ati Abiatari si li awọn alufa.

26 Ira pẹlu, ara Jairi ni nṣe alufa lọdọ Dafidi.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan