2 Samuẹli 14 - Bibeli MimọJoabu ṣe ètò àtipadà Absalomu 1 JOABU ọmọ Seruia si kiyesi i pe, ọkàn ọba si fà si Absalomu. 2 Joabu si ranṣẹ si Tekoa, o si mu ọlọgbọn obinrin kan lati ibẹ̀ wá, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, ṣe bi ẹniti nṣọfọ, ki o si fi aṣọ ọfọ sara, ki o má si ṣe fi ororo pa ara, ki o si dabi obinrin ti o ti nṣọ̀fọ fun okú li ọjọ pupọ̀. 3 Ki o si tọ̀ ọba wá, ki o si sọ fun u gẹgẹ bi ọ̀rọ yi. Joabu si fi ọ̀rọ si i li ẹnu. 4 Nigbati obinrin ará Tekoa na si nfẹ sọ̀rọ fun ọba, o wolẹ, o dojubolẹ, o si bu ọla fun u, o si wipe, Ọba, gbà mi. 5 Ọba si bi i lere pe, Ki li o ṣe ọ? on si dahùn wipe, Nitõtọ, opó li emi iṣe, ọkọ mi si kú. 6 Iranṣẹbinrin rẹ si ti li ọmọkunrin meji, awọn mejeji si jọ jà li oko, kò si si ẹniti yio là wọn, ekini si lu ekeji, o si pa a. 7 Si wõ, gbogbo idile dide si iranṣẹbinrin rẹ, nwọn si wipe, Fi ẹni ti o pa ẹnikeji rẹ̀ fun wa, awa o si pa a ni ipo ẹmi ẹnikeji rẹ̀ ti o pa, awa o si pa arole na run pẹlu: nwọn o si pa iná mi ti o kù, nwọn kì yio si fi orukọ tabi ẹni ti o kù silẹ fun ọkọ mi li aiye. 8 Ọba si wi fun obinrin na pe, Lọ si ile rẹ, emi o si kilọ nitori rẹ. 9 Obinrin ara Tekoa na si wi fun ọba pe, Oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀ṣẹ na ki o wà lori mi, ati lori idile baba mi; ki ọba ati itẹ rẹ̀ ki o jẹ́ alailẹbi. 10 Ọba si wipe, Ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ si ọ, mu oluwa rẹ̀ tọ̀ mi wá, on kì yio si tọ́ ọ mọ. 11 O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba ki o ranti Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ki olugbẹsan ẹjẹ ki o máṣe ni ipa lati ṣe iparun, ki nwọn ki o má bà pa ọmọ mi; on si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkan ninu irun ori ọmọ rẹ ki yio bọ́ silẹ, 12 Obinrin na si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o sọ̀rọ kan fun oluwa mi ọba; on si wipe, Ma wi. 13 Obinrin na si wipe, Nitori kini iwọ si ṣe ro iru nkan yi si awọn enia Ọlọrun? nitoripe ọba si sọ nkan yi bi ẹniti o jẹbi, nitipe ọba kò mu isánsa rẹ̀ bọ̀ wá ile. 14 Nitoripe awa o sa kú, a o si dabi omi ti a tú silẹ ti a kò si le ṣajọ mọ; nitori bi Ọlọrun kò ti gbà ẹmi rẹ̀, o si ti ṣe ọna ki a má bà lé isánsa rẹ̀ kuro lọdọ rẹ̀. 15 Njẹ nitorina li emi si ṣe wá isọ nkan yi fun oluwa mi ọba, bi o jẹpe awọn enia ti dẹrubà mi; iranṣẹbinrin rẹ si wi pe, Njẹ emi o sọ fun ọba; o le ri bẹ̃ pe ọba yio ṣe ifẹ iranṣẹbinrin rẹ̀ fun u. 16 Nitoripe ọba o gbọ́, lati gbà iranṣẹbinrin rẹ̀ silẹ lọwọ ọkunrin na ti o nfẹ ke emi ati ọmọ mi pẹlu kuro ninu ilẹ ini Ọlọrun. 17 Iranṣẹbinrin rẹ si wipe, Njẹ ọ̀rọ ọba oluwa mi yio si jasi itùnu: nitori bi angeli Ọlọrun bẹ̃ ni oluwa mi ọba lati mọ̀ rere ati buburu: Oluwa Ọlọrun rẹ yio si wà pẹlu rẹ. 18 Ọba si dahùn, o si wi fun obinrin na pe, Máṣe fi nkan ti emi o bere lọwọ rẹ pamọ fun mi, emi bẹ̀ ọ. Obinrin na si wipe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mã wi. 19 Ọba si wipe, Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹlu rẹ ninu gbogbo eyi? obinrin na si dahun o si wipe, Bi ẹmi rẹ ti mbẹ lãye, oluwa mi ọba, kò si iyipada si ọwọ́ ọtun, tabi si ọwọ́ osi ninu gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti wi: nitoripe Joabu iranṣẹ rẹ, on li o rán mi, on li o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi si iranṣẹbinrin rẹ li ẹnu. 20 Lati mu iru ọ̀rọ wọnyi wá ni Joabu iranṣẹ rẹ si ṣe nkan yi: oluwa mi si gbọ́n, gẹgẹ bi ọgbọ́n angeli Ọlọrun, lati mọ̀ gbogbo nkan ti mbẹ li aiye. 21 Ọba si wi fun Joabu pe, Wõ, emi o ṣe nkan yi: nitorina lọ, ki o si mu ọmọdekunrin na Absalomu pada wá. 22 Joabu si wolẹ o doju rẹ̀ bolẹ, o si tẹriba fun u, o si sure fun ọba: Joabu si wipe, Loni ni iranṣẹ rẹ mọ̀ pe, emi ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, oluwa mi, ọba, nitoripe ọba ṣe ifẹ iranṣẹ rẹ. 23 Joabu si dide, o si lọ si Geṣuri, o si mu Absalomu wá si Jerusalemu. 24 Ọba si wipe, Jẹ ki o yipada lọ si ile rẹ̀, má si ṣe jẹ ki o ri oju mi. Absalomu si yipada si ile rẹ̀, kò si ri oju ọba. 25 Kò si si arẹwà kan ni gbogbo Israeli ti a ba yìn bi Absalomu: lati atẹlẹsẹ rẹ̀ titi de atari rẹ̀ kò si abùkun kan lara rẹ̀. Ìjà Parí láàrin Absalomu ati Dafidi 26 Nigbati o ba si rẹ́ irun ori rẹ̀ (nitoripe li ọdọdun li on ima rẹ́ ẹ nitoriti o wuwo fun u, on a si ma rẹ́ ẹ) on si wọ̀n irun ori rẹ̀, o si jasi igba ṣekeli ninu òṣuwọn ọba. 27 A si bi ọmọkunrin mẹta fun Absalomu ati ọmọbinrin kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari: on si jẹ obinrin ti o li ẹwà loju. 28 Absalomu si joko li ọdun meji ni Jerusalemu kò si ri oju ọba. 29 Absalomu si ranṣẹ si Joabu, lati rán a si ọba; ṣugbọn on kò fẹ wá sọdọ rẹ̀; o si ranṣẹ lẹ̃keji on kò si fẹ wá. 30 O si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, oko Joabu gbè ti emi, o si ni ọkà nibẹ; ẹ lọ ki ẹ si tinabọ̀ ọ. Awọn iranṣẹ Absalomu si tinabọ oko na. 31 Joabu si dide, o si tọ Absalomu wá ni ile, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti awọn iranṣẹ rẹ fi tinabọ oko mi? 32 Absalomu si da Joabu lohùn pe, Wõ, emi ranṣẹ si ọ, wipe, Wá nihinyi, emi o si rán ọ lọ sọdọ ọba, lati wi pe, Kili emi ti Geṣuri wá si? iba sàn fun mi bi o ṣepe emi wà nibẹ̀ sibẹ. Njẹ emi nfẹ ri oju ọba; bi o ba si ṣe pe ẹ̀ṣẹ mbẹ li ara mi, ki o pa mi. 33 Joabu si tọ̀ ọba wá, o si rò fun u: o si ranṣẹ pe Absalomu, on si wá sọdọ ọba, o tẹriba fun u, o si doju rẹ̀ bolẹ niwaju ọba; ọba si fi ẹnu ko Absalomu li ẹnu. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria