2 Kronika 3 - Bibeli Mimọ1 SOLOMONI si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu li òke Moriah nibiti Ọlọrun farahàn Dafidi baba rẹ̀, ti Dafidi ti pèse, nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi. 2 On si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile ni ọjọ keji oṣù keji, li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀. 3 Eyi si ni ìwọn ti Solomoni fi lelẹ fun kikọ́ ile Ọlọrun. Gigùn rẹ̀ ni igbọnwọ gẹgẹ bi ìwọn igbãni li ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ. 4 Ati iloro ti mbẹ niwaju ile na, gigùn rẹ̀ ri gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgọfa; o si fi kiki wura bò o ninu. 5 O si fi igi-firi bò ile ti o tobi, o si fi wura daradara bò o, o si gbẹ́ àworan igi-ọpẹ ati ẹ̀wọn si i. 6 O si fi okuta iyebiye ṣe ile na li ọṣọ́ fun ẹwà: wura na si jasi wura Parfaimu. 7 O si fi wura bò ile na pẹlu, ati ìti, opó, ati ogiri rẹ̀ wọnni, ati ilẹkun rẹ̀ mejeji; o si gbẹ́ àworan awọn kerubu si ara ogiri na. 8 O si ṣe ile mimọ́-jùlọ na, gigùn eyiti o wà gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ: ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ: o si fi wura daradara bò o, ti o to ẹgbẹta talenti. 9 Oṣuwọn iṣó si jasi ãdọta ṣekeli wura. On si fi wura bò iyara òke wọnni. 10 Ati ninu ile mimọ́-jùlọ na, o ṣe kerubu meji ti iṣẹ ọnà finfin, o si fi wura bò wọn. 11 Iyẹ awọn kerubu na si jẹ ogún igbọnwọ ni gigùn: iyẹ kan jẹ igbọnwọ marun, ti o kan ogiri ile na, iyẹ keji si jẹ igbọnwọ marun, ti o kan iyẹ kerubu keji. 12 Ati iyẹ kerubu keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan ogiri ile na: ati iyẹ keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan iyẹ kerubu keji. 13 Iyẹ kerubu wọnyi nà jade ni ogún igbọnwọ: nwọn si duro li ẹsẹ wọn, oju wọn si wà kọju si ile. 14 O si ṣe iboju alaro, ati elése aluko ati òdodó, ati ọ̀gbọ daradara, o si ṣiṣẹ awọn kerubu lara wọn. Àwọn Òpó Idẹ Meji ( I. A. Ọba 7:15-22 ) 15 O si ṣe ọwọ̀n meji igbọnwọ marundilogoji ni giga niwaju ile na, ati ipari ti mbẹ lori ọkọkan wọn si jẹ igbọnwọ marun. 16 O si ṣe ẹ̀wọn ninu ibi-idahùn na, o si fi wọn si ori awọn ọwọ̀n na: o si ṣe awọn pomegranate ọgọrun, o si fi wọn si ara ẹ̀wọn na. 17 O si gbé awọn ọwọ̀n na ro niwaju ile Ọlọrun, ọkan li apa ọtún, ati ekeji li apa òsi, o si pe orukọ eyi ti mbẹ li apa ọtún ni Jakini, ati orukọ eyi ti mbẹ li apa òsi ni Boasi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria