1 Kronika 14 - Bibeli MimọAkitiyan Dafidi ní Jerusalẹmu ( II. Sam 5:11-16 ) 1 HIRAMU ọba Tire si ran onṣẹ si Dafidi, ati igi Kedari, pẹlu awọn ọmọle ati gbẹnagbẹna, lati kọ́le fun u. 2 Dafidi si woye pe, Oluwa ti fi idi on joko li ọba lori Israeli, nitori a gbé ijọba rẹ̀ ga nitori ti awọn enia rẹ̀, Israeli. 3 Dafidi si mu awọn aya si i ni Jerusalemu: Dafidi si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin si i. 4 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ti o ni ni Jerusalemu; Ṣammua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni, 5 Ati Ibhari, ati Eliṣua, ati Elpaleti, 6 Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia, 7 Ati Eliṣama, ati Beeliada, ati Elifaleti. Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Filistia ( II. Sam 5:17-25 ) 8 Nigbati awọn ara Filistia si gbọ́ pe, a fi ororo yan Dafidi li ọba lori gbogbo Israeli, gbogbo awọn ara Filistia gòke lọ iwá Dafidi: Dafidi si gbọ́, o si jade tọ̀ wọn. 9 Awọn ara Filistia si wá, nwọn si tẹ ara wọn ni afonifoji Refaimu. 10 Dafidi si bere lọdọ Ọlọrun wipe, Ki emi ki o gòke tọ awọn ara Filistia lọ? Iwọ o ha fi wọn le mi lọwọ? Oluwa si wi fun u pe, Gòke lọ, emi o si fi wọn le ọ lọwọ. 11 Bẹ̃ni nwọn gòke lọ si Baal-perasimu; Dafidi si kọlù wọn nibẹ. Dafidi si wipe, Ọlọrun ti ti ọwọ mi yà lu awọn ọta mi bi yiya omi: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ na ni Baal-perasimu. 12 Nwọn si fi awọn orisa wọn silẹ nibẹ, Dafidi si wipe, ki a fi iná sun wọn. 13 Awọn ara Filistia si tun tẹ ara wọn kakiri ni afonifoji. 14 Nitorina ni Dafidi tun bère lọwọ Ọlọrun: Ọlọrun si wi fun u pe, Máṣe gòke tọ̀ wọn; yipada kuro lọdọ wọn, ki o si ja lu wọn niwaju igi mulberi. 15 Yio si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lòke igi mulberi, nigbana ni ki iwọ ki o gbogun jade: nitori Ọlọrun jade ṣaju rẹ lọ lati kọlù ogun awọn ara Filistia. 16 Dafidi si ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun u: nwọn si kọlù ogun awọn ara Filistia lati Gibeoni titi de Gaseri. 17 Okiki Dafidi si kan yi gbogbo ilẹ ka. Oluwa si mu ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o ba gbogbo orilẹ-ède. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria