Esteri 9:19 - Yoruba Bible19 Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn. See the chapterBibeli Mimọ19 Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀. See the chapterBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní19 Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn. See the chapter |