Daniẹli 2:9 - Yoruba Bible9 Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” See the chapterBibeli Mimọ9 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi, njẹ ipinnu kan li ẹnyin ti ṣe: nitoriti ẹnyin mura lati ma sọ̀rọ eke ati idibajẹ niwaju mi, titi akoko yio fi kọja: nitorina ẹ rọ́ alá na fun mi emi o si mọ̀ pe ẹnyin o le fi itumọ̀ rẹ̀ hàn fun mi pẹlu. See the chapterBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè si ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.” See the chapter |