Rutu 2:20 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní20 Naomi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.” See the chapterYoruba Bible20 Naomi dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA tí kì í gbàgbé láti ṣàánú ati òkú ọ̀run, ati alààyè bukun Boasi.” Naomi bá ṣe àlàyé fún Rutu pé, ẹbí àwọn ni Boasi, ati pé ọ̀kan ninu àwọn tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí ni. See the chapterBibeli Mimọ20 Naomi si wi fun aya-ọmọ rẹ̀ pe, Ibukún ni fun u lati ọdọ OLUWA wá, ẹniti kò dẹkun ore rẹ̀ lati ṣe fun awọn alãye, ati fun awọn okú. Naomi si wi fun u pe, ọkunrin na sunmọ wa, ibatan ti o sunmọ wa ni. See the chapter |