Numeri 7:88 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní88 Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan. Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i. See the chapterYoruba Bible88 Àwọn nǹkan tí wọ́n kó kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia ni: akọ mààlúù mẹrinlelogun pẹlu ọgọta àgbò; ọgọta òbúkọ, ọgọta ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n kó gbogbo wọn wá fún ọrẹ ẹbọ fún yíya pẹpẹ sí mímọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ta òróró sí i. See the chapterBibeli Mimọ88 Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i. See the chapter |