Esteri 6:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Nígbà tí Hamani wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?” Nísinsin yìí Hamani sì ro èyí fúnrarẹ̀ pé, “Ta ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?” See the chapterYoruba Bible6 Bí Hamani tí ń wọlé ni ọba bi í pé, “Kí ló yẹ kí á ṣe fún ẹni tí inú ọba dùn sí?” Hamani rò ó ninu ara rẹ̀ pé, ta ni ọba ìbá tún dá lọ́lá bíkòṣe òun. See the chapterBibeli Mimọ6 Bẹ̃ni Hamani si wọle wá, Ọba si wi fun u pe, kini a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun? Njẹ Hamani rò ninu ọkàn ara rẹ̀ pe, Tani inu ọba le dùn si lati bù ọlá fun jù emi tikalami lọ? See the chapter |