Esteri 2:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní21 Ní àsìkò tí Mordekai jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba, Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Ahaswerusi. See the chapterYoruba Bible21 Ní àkókò náà, nígbà tí Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin, meji ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà: Bigitana ati Tereṣi, ń bínú sí ọba, wọ́n sì ń dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba. See the chapterBibeli Mimọ21 Li ọjọ wọnni, nigbati Mordekai njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba, meji ninu awọn iwẹfa ọba, Bigtani ati Tereṣi, ninu awọn ti nṣọ iloro, nwọn binu, nwọn si nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba. See the chapter |