Eksodu 7:19 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní19 Olúwa sọ fún Mose, “Sọ fún Aaroni, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Ejibiti. Lórí àwọn odò kéékèèkéé àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi, wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Ejibiti, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.” See the chapterYoruba Bible19 OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó mú ọ̀pá rẹ̀, kí ó sì nà án sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ati sórí odò wọn, ati sórí adágún tí wọ́n gbẹ́, ati gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ yóo sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti; ati omi tí ó wà ninu agbada tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati tinú agbada tí wọ́n fi òkúta gbẹ́.” See the chapterBibeli Mimọ19 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta. See the chapter |