Eksodu 3:18 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní18 “Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’ See the chapterYoruba Bible18 “Wọn yóo gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, ìwọ ati àwọn àgbààgbà Israẹli yóo tọ ọba Ijipti lọ, ẹ óo sì wí fún un pé, ‘OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ti wá bá wa, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á lọ sinu aṣálẹ̀, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè rúbọ sí OLUWA, Ọlọrun wa.’ See the chapterBibeli Mimọ18 Nwọn o si fetisi ohùn rẹ: iwọ o si wá, iwọ ati awọn àgba Israeli, sọdọ ọba Egipti, ẹnyin o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu pade wa: jẹ ki a lọ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki awa ki o le rubọ si OLUWA Ọlọrun wa. See the chapter |