Daniẹli 3:29 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní29 Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀-èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.” See the chapterYoruba Bible29 “Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.” See the chapterBibeli Mimọ29 Nitorina, emi paṣẹ pe, olukulùku enia, orilẹ, ati ède, ti o ba sọ ọ̀rọ odi si Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, a o ke e wẹwẹ, a o si sọ ile rẹ̀ di àtan: nitori kò si Ọlọrun miran ti o le gbà ni là bi iru eyi. See the chapter |