Esteri 8:8 - Bibeli Mimọ8 Ẹnyin kọwe ẹ̀wẹ li orukọ ọba, nitori awọn Ju bi ẹnyin ti fẹ́, ki ẹ si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀: nitori iwe ti a ba fi orukọ ọba kọ, ti a ba si fi òruka ọba ṣe edidi, ẹnikan kò le yi i pada. See the chapterYoruba Bible8 Kọ ohunkohun tí ó bá wù ọ́ nípa àwọn Juu ní orúkọ ọba, kí o sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Nítorí pé òfin tí a bá kọ ní orúkọ ọba, tí ó sì ní èdìdì ọba, ẹnikẹ́ni kò lè yí i pada mọ́.” See the chapterBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Nísinsin yìí, kọ ìwé àṣẹ mìíràn ní orúkọ ọba bí àwọn Júù ṣe jẹ́ pàtàkì sí ọ, kí o sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì dì í, nítorí kò sí àkọsílẹ̀ tí a bá ti kọ ní orúkọ ọba tí a sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì tí a lè yìí padà.” See the chapter |