Daniẹli 4:33 - Bibeli Mimọ33 Ni wakati kanna ni nkan na si ṣẹ si Nebukadnessari, a si le e kuro larin enia, o si jẹ koriko bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, titi irun ori rẹ̀ fi kún gẹgẹ bi iyẹ idì, ẽkana rẹ̀ si dabi ti ẹiyẹ. See the chapterYoruba Bible33 Lẹsẹkẹsẹ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹ mọ́ Nebukadinesari lára. Wọ́n lé e kúrò láàrin àwọn eniyan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko bíi mààlúù. Ìrì sẹ̀ sí i lára títí tí irun orí rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, èékánná rẹ̀ sì dàbí ti ẹyẹ. See the chapterBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní33 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ. See the chapter |