Daniẹli 2:45 - Bibeli Mimọ45 Gẹgẹ bi iwọ si ti ri ti okuta na wá laisi ọwọ lati òke wá, ti o si fọ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wura wọnni tutu; Ọlọrun titobi ti fi hàn fun ọba, ohun ti mbọ wá ṣe lẹhin ọla: otitọ si li alá na, itumọ rẹ̀ si daju. See the chapterYoruba Bible45 Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.” See the chapterBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní45 Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́. “Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.” See the chapter |