Daniẹli 2:35 - Bibeli Mimọ35 Nigbana li a si fọ irin, amọ̀, idẹ, fadaka ati wura pọ̀ tũtu, o si dabi iyangbo ipaka nigba ẹ̀run; afẹfẹ si gbá wọn lọ, ti a kò si ri ibi kan fun wọn mọ́: okuta ti o si fọ ere na si di òke nla, o si kún gbogbo aiye. See the chapterYoruba Bible35 Lẹ́sẹ̀kan náà òkúta yìí bá fọ́ gbogbo ère náà, ati irin, ati amọ̀, ati idẹ, ati fadaka ati wúrà, ó rún gbogbo wọn wómúwómú, títí wọ́n fi dàbí ìyàngbò ní ibi ìpakà. Lẹ́yìn náà, afẹ́fẹ́ fẹ́ wọn lọ, a kò sì rí wọn mọ́ rárá. Òkúta tí ó kọlu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé. See the chapterBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní35 Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé. See the chapter |