Mika 1:11 - Yoruba Bible11 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Ṣafiri ẹ máa rìn ní ìhòòhò pẹlu ìtìjú lọ sí ìgbèkùn. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Saanani, ẹ má jáde kúrò níbẹ̀, nítorí ẹkún àwọn ará Beteseli, yóo fihàn yín pé kò sí ààbò yín lọ́dọ̀ wọn. Viz kapitolaBibeli Mimọ11 Ẹ kọja lọ, iwọ ará Safiri, pẹlu itiju rẹ ni ihòhò: ara Saanani kò jade wá; ọ̀fọ̀ Beteseli yio gba iduro rẹ̀ lọwọ nyin. Viz kapitolaBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú, ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri. Àwọn tí ó ń gbé ni Ṣaanani kì yóò sì jáde wá. Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀; A ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin. Viz kapitola |