Isaiah 1:6 - Yoruba Bible6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín, kò síbìkan tí ó gbádùn. Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn. Viz kapitolaBibeli Mimọ6 Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn. Viz kapitolaBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró. Viz kapitola |